Ẹ woju Wolii Festus to fẹẹ fọmọ wolii ẹgbẹ ẹ ṣoogun l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ ọmọbinrin kan ti ọrẹkunrin rẹ, Gbemisọla Ọlafusi, ati Wolii Adebayọ Festus fẹẹ fi ṣoogun niluu Ondo.

ALAROYE gbọ pe ni kete tọwọ awọn ọlọpaa tesan Ẹnuọwa tẹ awọn mejeeji ni wọn ti jẹwọ ipa ti ọkọọkan wọn ko lori ọrọ akẹkọọ ọhun.

Ọlafusi, afurasi keji

Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ to kọja, ni wọn fi awọn afurasi naa ṣọwọ si olu ileesẹ ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, niluu Akurẹ, fun itẹsiwaju ifọrọwanilẹnuwo ti wọn n ṣe fun wọn.

Ọṣẹ yii kan naa ni wọn gba beeli Wolii Festus, to si pada siluu Ondo lẹyin to ṣeleri ati tọju ọmọbinrin ọhun laarin ọṣẹ meji pere, nigba ti Ọlafusi ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa l’Akurẹ.

A gbọ pe wolii yii ti bẹrẹ si i tọju akẹkọọ naa lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ṣugbọn a ko ti i rẹni ṣọ fun wa boya o ti n gbadun tabi bẹẹ kọ.

Wolii Festus ti wọn fẹsun kan ni wọn lo jẹ oludasilẹ ijọ Kerubu ati Ṣerafu to wa lagbegbe Ọgbọntitun, niluu Ondo.

Ohun to n ya awọn eeyan lẹnu ju ni bo ṣe jẹ pe ọmọ agba wolii mi-in, Aposteli Iluyọmade Festus, lo fẹẹ fi ṣoogun fun onibaara rẹ.

Wọn ni paadi nnkan osu ọmọbinrin ọhun ti wọn fi ṣoogun ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

One thought on “Ẹ woju Wolii Festus to fẹẹ fọmọ wolii ẹgbẹ ẹ ṣoogun l’Ondo

Leave a Reply