Ẹ woju wọn, awọn ni wọn pa Barakat, ti wọn tun pa alaboyun atawọn mi-in l’Akinyẹle, n’Ibadan

 

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni gbogbo awọn to wa nibi tawọn ọlọpaa ti ṣafihan awọn mẹta kan tọwọ tẹ pe awọn ni wọn ti n paayan l’Akinyẹle, niluu Ibadan, lọrọ naa ṣi n ya lẹnu.

Niṣe lawọn eeyan naa, Sunday Adedipẹ, Adedokun Yinusa ati Usman n ka boroboro pe awọn lawọn wa nidii awọn eeyan ti wọn n ṣa ladaa pa l’Akinyẹle, n’Ibadan.

Ọkan ninu wọn, Sunday Adedipẹ, jẹwọ pe eeyan meje loun ti pa, ati pe oogun lawọn maa n lo toun ba fẹẹ pa awọn eeyan naa, idi niyi ti wọn ki i fi i ri oun.

O ni Adedokun Yinusa lo maa n ran oun niṣẹ lati lọọ pa awọn eeyan naa, lẹyin toun ba si pa wọn tan lo maa fun oun ni ẹẹdẹgbẹta naira, yoo si tun ti pese ounjẹ toun maa jẹ silẹ foun.

Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwachukwu, ṣafihan wọn.

Usman ni wọn kọkọ mu. Ohun to si tu u fo ni foonu obinrin alaboyun ti wọn pa ni Abule Ijẹfun ti wọn ba lọwọ rẹ. Oun lo si ṣatọna bi wọn ṣe ri Sunday ati Adedokun mu.

Ẹ foju sọna fun ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ ti ALAROYE ṣe pẹlu awọn eeyan naa.

 

Leave a Reply