Ẹ woju wọn o: Awọn ọmọde Fulani adigunjale lọna Ibadan

Awọn Fulani ọmọde kan ti wọn ko ti i pe ọmo ogun ọdun ti wa lọna Ibadan bayii o, ogbologboo adigunjale ni wọn. Ohun ti wọn maa n se ni pe wọn yoo rọ jana lẹẹkan naa lati fi tipatipa da mọto to ba n bọ duro, ti mọto naa ba si ti duro ni wọn yoo sare si i pẹlu kumọ, ọbẹ ati awọn ohun ija oloro mi-in, wọn yoo si gba gbogbo ohun tawọn ero inu mọto naa ba ko dani, wọn si le wọ awọn mi-in lọ sinu igbo ninu awọn ero naa ki wọn too gba tọwọ wọn.

Awon omo Fulani towo te

Ọwọ ti tẹ awọn mẹta ninu wọn o. Ana ode yii ni alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, sọ bẹẹ. Oyeyẹmi ni nitosi Alapako,  lọna marosẹ Eko s’Ibadan, lawọn adigunjale naa ti rọ ja oju ọna, ti wọn si fipa da mọto bọọsi akero kan duro, ni wọn ba bẹrẹ si i ko kumọ bo awọn ti wọn wa nibẹ, ti wọn si n ja gbogbo ohun to wa lọwọ wọn gba. Ẹni kan lo sare pe awọn ọlọpaa Owode Ẹgba, ni DPO wọn, Mathew Ediae, ba ṣaaju awọn ọlopaa ẹ, ni wọn ba gba ibẹ lọ.

Wọn ṣii ba awọn adigunjale na anitosi ibẹ ti wọn n ṣiṣe wọn, igba ti wọn si ri awọn ọlọpaa ni wọn sa wọnu igbo lọ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa naa gba tọ wọn, wọn si mu awọn mẹta ninu wọn. Ẹnu ya wọn pe awọn ọmọ Fulani ti ko ti i sẹni to pe ogun ọdun ninu wọn lawọn mẹtẹẹta. Ayuba Buhari, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Adamu Yakubu, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Uzeifa Idris ọmọ ọdun mọkandinlogun.

Awọn ọ̀ọpaa ni wọn gba dẹrẹba mọto naa, Zacheaus Ọlaniyi lọwọ awon Fulani adigunjale yii, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹdẹgbẹta ati marun Naira (N545,000) owo Oluwakẹmi Ogungbade ti wọn ti ja gba lọwọ wọn pada. Bẹ ẹ ba n gba ọna Ibadan, ẹ maa fura, nitori awọn Fulani adigunjale yii o.

Leave a Reply