Ẹbi Fawẹhinmi ti kede isinku Muhammed, wọn ni Korona lo pa a

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn ẹbi gbajugbaja amofin nni, Gani Fawẹhinmi, ti kede bi wọn yoo ṣe sinku ọmọ wọn, Muhammed Fawẹhinmi, to doloogbe laipẹ yii, bẹẹ ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe aisan Korona lo gba ẹmi ọkunrin naa.

Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ yii, ni ẹbi Fawẹhinmi fidi eyi mulẹ nibi ipade oniroyin ti wọn pe, nibẹ ni Saheed Fawẹhinmi, ọkan ninu awọn ọmọ agba amofin naa ti ṣalaye fawọn akọroyin pe idi meji tawọn fi pepade yii ni lati ṣalaye iru iku to pa Daodu ile Fawẹhinmi, kawọn si sọ bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ.

Ọgbẹni Saheed Fawẹhinmi sọ pe awọn ko tete sọ iru iku to pa Muhammed nitori awọn fẹẹ fidi ẹ mulẹ latọdọ awọn dokita oyinbo, ohun to pamọ naa si ti waa foju han lẹyin ayẹwo bayii, awọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe Korona lo pa Muhammed, ololufẹ awọn.

Fun idi eyi, idile Fawẹhinmi lawọn rọ awọn ọmọ Naijiria, ki wọn ṣọra lori ọrọ Koro. Wọn ni beeyan ba ti gba abẹrẹ to n dena Korona yii paapaa, ko tun ṣọra ṣe, ko maa lo ibomu rẹ, ko si jinna si gbogbo ohun to le mu Koro wọle.

Wọn rọ ijọba pẹlu lati ṣeto to yẹ nipa aisan yii, ki wọn si kede ẹ pe kinni buruku naa ṣi n ṣọṣẹ, ki awọn ti wọn ti ni aisan kan tabi omi-in lara tẹlẹ to le tete jẹ ki Koro pa wọn le tete maa ṣọra wọn. Bakan naa ni wọn ni kijọba da awọn dokita to n yanṣẹ lodi yii lohun, ki wọn wo bi Oloogbe ati baba rẹ ṣe ja fẹtọọ ọmọniyan ki wọn too faye silẹ, kijọba ṣe ohun to yẹ lasiko to yẹ.

Nipa bi isinku Oloogbe Muhammed yoo ṣe lọ, isin orin ati sisọ ọrọ iwuri nipa Oloogbe yoo waye l’Ọjọruu, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ni ṣọọṣi  Archbishop Vining Cathedral, Ikẹja, niluu Eko. Aago mẹrin irọlẹ si aago meje alẹ ni eyi yoo fi waye.

To ba di l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, wọn yoo gbe oku lati Eko lọ si agboole Fawẹhinmi, l’Ondo. To ba waa di lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, wọn yoo sin ọkunrin lọọya to ku lẹni ọdun mejilelaaadọta ọhun si agboole Fawẹhimi, l’Ondo.

Awọn ẹbi yii lawọn dupẹ lọwọ gbogbo awọn abanikẹdun latijọ yii wa, awọn si faaye gba awọn to ba fẹẹ lọ s’Ondo lati ṣeto isinku. Wọn ni ṣugbọn yoo dun m’awọn bi ero ba mọ niwọn, nitori ofin to de sinsin oku ẹni ti Korona pa.

Leave a Reply