Ebi lo ti wa sita, ẹgbẹ oṣelu kan kọ lo n lo wa – Oṣiṣẹ-fẹyinti Ọṣun

Florence Babasola, Oṣogbo

Agbarijọpọ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọṣun ti wọn fọn sita laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lati fẹhonu han lori owo mọdamọda pẹnṣan wọn (Contributory Pension) ati ajẹsilẹ owo-oṣu tijọba jẹ wọn ni wọn ti sọ gbangba pe ko si ẹnikankan to n lo awọn lati ta ko ijọba, bi ko ṣe ebi to n pa awọn ninu ile.

Ọkan lara awọn agbẹnusọ wọn, Alagba Adeyẹmi Ṣọbaloju, ṣalaye fun akọroyin wa pe o ti pe oṣu mẹrindinlọgọta ti oun ti fẹyinti, lẹyin ti oun lo ọdun marundinlogoji lẹnu iṣẹ ijọba l’Ọṣun, sibẹ oun ko ti i ri tọrọ to n yọ gba.

O ṣalaye pe ẹgbẹrun mẹfa o din diẹ ni gbogbo awọn to kopa ninu eto mọdamọda pẹnṣan ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla gbe wa nigba naa, ṣugbọn ijọba kọ lati san owo naa fun awọn.

“Ṣebi Yoruba maa n sọ pe ori ki i fọ ajọ ni? L’Ọṣun, ori ti n fọ ajọ, ọrun ti n wọ ọ bayii. Odidi ọgbọn oṣu la fi gba idaji owo-oṣu (half salaries), wọn tun wa n sọ pe o di ọdun to n bọ kawọn too da wa lohun.

“Oloṣelu kankan ko ṣonigbọwọ wa o, ebi ati iku lo ṣonigbọwọ wa debi. O ti di okoolelẹẹẹdẹgbẹrin eeyan to ti ku lara wa, awọn ara ọsibitu ko gba wa mọ, wọn ni onigbese ni wa, ẹni kan tun ku laaarọ yii lara wa, ọdun lo tun n bọ yii o, ki wọn fun wa lowo wa, aijẹ bẹẹ, ikoko ko ni i gba ṣọṣọ ko tun gba ẹyin o”

Bakan naa, Comrade Kọlade Oloyede Amos ṣalaye pe ariwo lasan nijọba n pa lori owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ti wọn sọ pe awọn san laipẹ yii, o ni ki i ṣe awọn oṣiṣẹ-fẹyinti tijọba ana, Arẹgbẹṣọla ko sinu mọdamọda ni wọn n sanwo fun. O si rọ ijọba lati tete da si ọrọ naa.

Ninu ọrọ Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, to waa awọn to n fẹhonu han sọrọ, o ni gbogbo eeyan lo mọ pe adiyẹ Gomina Oyetọla n laagun, ṣugbọn iyẹ ni ko jẹ ko han, o ni laipẹ nijọba yoo yanju ọrọ naa lẹyọ kọọkan.

Leave a Reply