Ẹẹmeji ni mo daku nigba ti mo kọkọ laju ri oku iyawo mi ni mọsuari-Ọlakunrin

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Pupọ ninu awọn ero to wa nile-ẹjọ giga, nibi ti igbejọ awọn afufasi ọdaran mẹrin ti wọn ṣeku pa Funkẹ Ọlakunrin ti n waye niluu Akurẹ ni wọn fẹrẹ le maa sunkun lasiko ti ọkọ oloogbe ọhun, Idowu Ọlakunrin, n royin ohun toju rẹ ri lọjọ ti wọn waa tufọ iku iyawo rẹ fun un.

Nigba ti agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni Leonard Ologun, pe ana olori Afẹnifẹre tẹlẹ ri ọhun siwaju gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ẹlẹrii, ibi to ti bẹrẹ ọrọ rẹ ni pe oun ko ni i fẹ ki ẹnikẹni maa tọka sì iyawo oun bíi oloogbe nitori pe oun si nigbagbọ pe awọn si jọ wa papọ.

O ni bíi ala ni iṣẹlẹ ọhun si n jọ loju oun nitori pe ko ju bii iṣẹju diẹ ti awọn si jọ sọrọ lori ago nigba ti ọkan ninu awọn ọmọ oun pe pe wọn ti yinbọn pa iyawo oun.

Ọlakunrin ni nigba ti ọrẹ oun ti awọn jọ wa ninu ọkọ lọjọ naa ṣakiyesi pe ara oun n gbọn lo gba ọkọ naa lọwọ oun, to si funra rẹ wa oun lọ sile.

O ni loju-ẹsẹ loun atawọn èèyàn kan gbera lati lọọ foju ara awọn ri ohun to ṣẹlẹ̀ gan-an niluu Ọrẹ.

Ẹẹmeji ọtọọtọ lo ni oun daku nigba toun foju kan oku iyawo oun ni ọsibitu ti wọn kọkọ gbe e lọ, o ni ṣe ni wọn gbe oun naa digba digba sinu ọkọ nigba tawọn eeyan tawọn jọ lọ fẹẹ maa gbe oku iya awọn ọmọ oun bọ l’Akurẹ lati tọju rẹ pamọ si mọṣuari ileewosan aladaani kan ti awọn ti ṣeto silẹ.

Awọn afurasi bíi mẹrin ni wọn ti n kawọ pọnyin rojọ lori bi wọn ṣe yinbọn pa ọmọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre tẹlẹ ọhun loju ọna marosẹ Ọrẹ si Ijẹbu-Ode lọdun bii meji sẹyin.

Mẹta ninu awọn olujẹjọ ọhun, Mohammed Shehu Usman, Masaje Lawal ati Adamu Adamu nijọba ipinlẹ Ondo n ba ṣẹjọ lori ẹsun bíi mẹsan-an ti wọn fi kan wọn, ninu eyi ti igbimọ-pọ da ẹsẹ nla, idigunjale, ijinigbe ati ipaniyan wa.

Ẹsun ṣiṣe onigbọwọ fun awọn ajinigbe ni wọn fi kan Awal Abubakar to jẹ ẹni kẹrin wọn.

Ọkunrin ọhun ni wọn lo ran afurasi kín-in-ni, Mohammad Sheu Usman, lọwọ lati ba a gbe owo ti wọn gba lọwọ ajinigbe pamọ lagbegbe Shasha, l’Akurẹ, laarin ọdun 2018 si oṣu keje, ọdun 2019.

Gbogbo awọn olujẹjọ naa ni lawọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Amofin G. A. Gbadamọsi lo n gbẹnusọ fun afurasi ọdaran kín-in-ni, nígbà ti Oloye Ọbafẹmi Bawa jẹ agbẹjọro fawọn mẹta yooku.

Ọgbọnjọ, osu ta a wa yii, ni Onidaajọ Williams Ọlamide ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply