Ọlawale Ajao, Ibadan
“Ọkọ mi ko mọ ju ounjẹ lọ, ọna ti mo gba rowo se ounjẹ ọhun ko kan an. Bo ṣe n ṣiṣẹ owo to, ki i ba mi da si bukaata ile. Ti mo ba bi i leere owo, niṣe lo maa bẹrẹ si i lu mi.”
Iyawo ile kan, Adenikẹ Bello, lo ṣe bayii sọrọ ni kootu ibilẹ Ọjaba, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja ninu ẹjọ to pe lati kọ ọkọ ẹ, Sheriff Bello silẹ.
Obinrin oniṣowo yii ṣalaye pe bi ko ba ṣe pe Ọlọrun ṣaanu oun ni, odidi oyun meji lọkọ oun iba ti bajẹ mọ oun lara, iyẹn bi ko ba tiẹ ti i gbẹmi oun gan-an paapaa nitori ẹẹmeji ọtọọtọ lọkunrin naa ti lu oun lasiko ti oun wa ninu oyun meji ọtọọtọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Èèwọ̀ ni fun ọkọ temi lati maa gbọ bukaata idile tiẹ. Tiẹ ni ko ṣaa ti maa ri ounjẹ jẹ, ko fẹẹ mọ ibikibi ti mo ti rowo se ounjẹ naa. Ọrọ ileewe awọn ọmọ paapaa ko kan an, awọn ọmọ gan-an ki i beere nnkan kan lọwọ ẹ nitori wọn ti mọ pe ko wulẹ ni i fun awọn.
“Ki i bọwọ fawọn obi mi rara, niṣe lo maa n ri wọn fin, to si maa n sọrọ si wọn ṣakaṣaka bo ṣe wu u. Nitori ẹ lawọn obi mi ko ṣe wa sile wa mọ.”
O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si ibaṣepọ oun ati Sheriff gẹgẹ bii tọkọ-taya. Bẹẹ lolujẹjọ paapaa fara mọ igbesẹ ọhun, o ni ibaṣepọ oun pẹlu obinrin naa ti su oun paapaa.
“Lati ọdun ti mo ti fẹ ẹ, mi o ri nnkan pataki kan bayii ti mo le tọka si gẹgẹ bii aṣeyọri mi. Gbogbo ohun to mọ ko ju ko maa ṣaroye lọ ṣaa, ko si maa fa wahala kaakiri adugbo. O tiẹ ti waa fẹẹ sọ ara ẹ di ọkọ mọ oluwa rẹ lọwọ ninu ile paapaa.” Bẹẹ ni Sheriff sọ ninu awijare tiẹ.
Igbimọ awọn adajọ kootu ọhun, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, ti tu igbeyawo ọlọmọ marun-un ọhun ka. Olujẹjọ ni wọn yọnda awọn mẹta akọkọ fun ninu awọn ọmọ naa, nigba ti wọn yọnda awọn meji to kere ju lọ ninu wọn fun iya wọn.
Oloye Ademọla waa pa olujẹjọ laṣẹ lati maa fun Adenikẹ, ẹni to ti di iyawo ẹ atijọ bayii lẹgbẹrun mẹfa Naira lati maa fi gbọ bukaata jijẹ mimu awọn ọmọ mejeeji ti wọn bi gbẹyin naa. Bẹẹ ni baba wọn tun gbọdọ maa mojuto eto ilera ati eto ẹkọ wọn loorekoore nipasẹ ile-ẹjọ.