Adewale Adeoye
‘‘Nigba akọkọ ti baba to bi mi lọmọ maa ja ibale mi, ọmọ ọdun mẹwaa pere ni mo wa lakooko naa, mi o mọ ohun to n ṣẹlẹ ati idi ti wọn fi ṣe bẹẹ si mi, mo fọrọ ọhun to mama mi leti, ki wọn le mọ ohun to n ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn naa ko gbe igbesẹ kankan nipa ọrọ yii rara. Mo si n ro o lọkan mi pe kin nidi ti wọn ko ṣe gbe igbesẹ lori ọrọ yii? ‘‘Nigba ti oju mi ko gba a mọ, mo tun wọn pe lẹẹkeji pe ki wọn waa gbọ ohun ti baba mi n ṣe pẹlu mi. Nnkan ti mama mi sọ fun mi ni pe ki n ṣe suuru, pe gbogbo rẹ aa niyanju laipẹ. Ni gbogbo akoko naa, mo ṣi kere gidi, emi paapaa ṣi lero pe ki i baba maa ba ọmọ rẹ sun gẹgẹ bi baba mi ṣe n ba mi sun bayii ki i ṣohun babara. Nigba ti ma a tun fi pe ọmọ ọdun mọkanla, wọn tun ba mi sun’. Eyi lọrọ to n jade lẹnu ọdọmọbirin kan to n sọ nipa awọn ohun toju rẹ ti ri lọwọ baba rẹ nigba to wa ni kekere.
Ninu ifọrọwero kan to waye laarin ọmọbinrin ti wọn ko darukọ rẹ yii to ṣe pẹ̀u akọroyin kan lo ti sọ pe nigba ti baba oun tun ki oun mọlẹ nigba keji, to si tun ba oun lajọṣepọ, loun ba beere idi to fi n ṣe bẹẹ, ti baba yii si sọ pe ki i ṣohun kan toju ko ri ri pe ki baba maa ba ọmọ to bi lajọṣepọ.
Ọmọbinrin ọhun sọ pe ni gbogbo akoko ti baba oun fi n b’oun sun yii, ko faaye gba oun lati ni ọrẹ tabi ki awọn eeyan waa ki oun nile rara.
‘Mi o lọrẹẹ Kankan, bẹẹ ni ko si ẹbi kan to maa n waa ki mi nile, ṣugbọn nigba to di oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti baba mi ran mi niṣẹ pe ki n lọọ ba awọn tun ẹrọ POS wọn ṣe ni mo ba gbiyanju lati lọọ fi ohun to n ṣe to awọn ọlọpaa leti boya wọn le ran mi lọwọ’’.
Ni idahun si ibeere ti akọroyin naa bi i pe o ṣe gba a lakooko to bẹẹ ko too lọọ fọrọ ọhun to ọlọpaa leti, ọmọbinrin yii ti sọ pe, ‘Ko sohun meji to mu mi dakẹ, ti mi o si gbe igbesẹ Kankan, ju pe bi mo ba sọrọ ọhun fun awọn eeyan lakooko naa, baba mi ko ni i sanwo idanwo aṣekagba WAEC mi, ẹkọ mi si wa lara awọn ohun to jẹ mi logun ju lọ.
‘‘Emi paapaa ti figba kan ro o lọkan mi pe bọya ki n sa lọ, nigba ti baba mi ko dawọ ibaṣepọ naa duro, ṣugbọn mo tun ro o wo pe ẹkọ mi maa ni ipalara gidi, iyẹn lọdun 2020. Ohun to dun mi ju ni pe ṣe ni baba mi sọ pe afi k’oun ba mi sun ko too di pe oun maa sanwo idanwo mi, eyi ti mo gba fun wọn lai ṣiyemeji’’.
Ẹẹmẹta laarin ọsẹ ni ọmọbinrin yii ni baba naa maa n ba oun lo pọ.
Ọdọ awọn ọlọpaa kan ni baba ọhun wa, nibi to ti n ṣalaye fun wọn nipa ohun to ri to fi jẹ pe ko ri ẹlomin-in ba laṣepọ ju ọmọ to bi ninu ara rẹ lọ.