Oludari ijọ kan ti wọn n pe ni Champions Royal Assembly, to wa niluu Abuja, Wolii Joshua Iginla, ti sọ pe ẹẹmẹta ọtọọtọ ni Ọlọrun ti fi han oun pe iranṣẹ Ọlọrun to lokiki kan maa ku, ati pe Wolii Temitọpẹ Balogun ti gbogbo eeyan mọ si TB Joshua ni.
Wolii yii ni Ọlọrun kọkọ fi iran naa han oun lọdun 2015, bẹẹ loun tun ri iran yii kan naa lọdun 2016 ati 2018. O ni bi iran yii ṣe waye naa loun pe TB Joshua, ti oun si ṣalaye iran naa fun un. Esi ti Joshua ti wọn tun n pe ni Sinagogu, iyẹn orukọ ṣọọṣi rẹ, fun Wolii Iginla ni pe, ‘‘O ṣeun, arakunrin mi, to ba jẹ ifẹ rẹ lati da mi si, yoo da mi si. Ko si ohunkohun to n ba mi lẹru mọ, mo ti ṣe awọn iṣẹ ti Ọlọrun ran mi wa sile aye lati waa ṣe. Mo maa tẹriba fun aṣẹ ati jijẹ alagbara to tobi ju Ọlọrun ni.’’
Iginla ṣapejuwe Joshua gẹgẹ bii ẹni to ni irẹlẹ, aṣoju to ni ifẹ awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ ati orisun ibukun fun ara Kristi.
Ọjọ Abamẹta, Satide ni ọkunrin naa ku lẹyin isin to ṣe pẹlu awọn ọmọ ijọ rẹ kan.