Eemọ lukutu pẹbẹ! Baba fọmọ bibi inu ẹ loyun, o lọmọ naa n da oun lọrun ni

Faith Adebọla, Ogun

Adajọ nikan lo le mọ iru sẹria toun yoo da fun baale ile afurasi ọdaran yii, Abiọdun Ọladapọ, ẹni ọdun mẹtalelogoji, amọ afaimọ nidajọ naa ko ni i ba ẹwọn gbere lọ, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe niṣe lọkunrin naa ki ọmọ bibi inu ẹ mọlẹ, ọmọbinrin tọjọ-ori ẹ ko ju mọkandinlogun pere lọ, o lọmọ naa n da oun lọrun, lo ba bẹrẹ si i fipa ba a lopọ, ere ni, awada ni, o ṣe ‘kinni’ ọhun debi tọmọbinrin yii fi d’abara-meji, oyun oṣu marun-un si duro sikun ẹ ni tepọn.

Yatọ si ti baba to jiṣu ọmọ bibi ẹ wa yii, wọn ni ẹgbọn ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun, Micheal Idowu, ti ṣe ‘kerewa’ fọmọ naa ri, bo tilẹ jẹ pe ọmọbinrin naa jẹwọ pe tẹgbọn oun yẹn ko ju ẹẹkan ṣoṣo lọ.

Iya Micheal ti wọn n sọ yii, Abilekọ Oluwatoyin Abiọdun, lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ naa han awọn ọlọpaa, nigba to lọọ fẹjọ sun lẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Mowe, nipinlẹ Ogun, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta yii, pe kawọn ọlọpaa waa bawọn da sọrọ to ṣẹlẹ ọhun, o ni wọn purọ mọ ọmọ oun, Micheal, pe o fun ọmọbinrin kan loyun, o lọrọ naa si ti n kari adugbo, bẹẹ, oun ti tẹ ọmọ oun ninu daadaa, o loun ko tiẹ ṣi ọmọbinrin ti wọn n sọ yii laṣọ wo ri, debi ọrọ oloyun de, tori ẹ loun ṣe mẹjọ wa si tọlọpaa ki wọn ma lọọ dẹbi ọrọ ti ki i ṣe tọmọ oun ru u, tori wọn ni ‘jẹẹjẹ ni mo jokoo mi,’ ki i jẹbi ẹjọ.

Loju-ẹsẹ, ni DPO Mowe, SP Fọlakẹ Afẹnifọrọ, ti yan awọn ọmọọṣẹ kan lati tẹle Iya Micheal, nigba ti wọn dọhun-un, wọn ri ọmọbinrin to diwọ-disẹ sinu ọhun, wọn si mu un lọ si teṣan wọn lati wadii ọrọ lẹnu ẹ, ki wọn le ri okodoro ọrọ, oloyun ṣaa gbọdọ mọ boun ṣe rin in tikun ẹ fi ga.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ s’ALAROYE lo ti ni ọmọbinrin naa jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ni tododo, baba to bi oun lọmọ, iyẹn Abiọdun Ọladapọ yii, lo foun loyun, o lo ti pẹ ti baba naa ti n yata lori oun, to si sọ foun pe niṣe ni kawọn jọ ṣe e lawo, oun o gbọdọ sọ fẹdaa Ọlọrun kan nipa ẹ, amọ mọ-ọn-gun, mọ-ọn-tẹ, iyan koko ko ni i ṣaila lẹmọ, igba tọrọ yiwọ mọ awọn lọwọ, ti oyun gbẹyin yọ, ni baba oun yii sọ pe koun purọ mọ ẹgbọn oun Micheal, p’oun lo foun loyun, eyi lo fa ariwo to n lọ nigboro pe Micheal fọmọbinrin kan loyun, to mu ki mama awọn bẹrẹ si i gbara ta.

Wọn tun bi sisi yii leere boya Micheal ti ṣi i laṣọ wo ri, o ni bẹẹ ni, ẹẹkan ṣoṣo pere loun ati ẹ jọ ṣere egele naa, amọ ti baba oun lo doyun, bo tilẹ jẹ pe baba naa mọ si ti Micheal toun n sọ yii.

Yooba bọ, wọn lọrọ to ba ti ṣoju ilu ko tun fara sin mọ, awọn ọlọpaa sọ ọ di mimọ pe iwadii tawọn ṣe ti fihan pe iya ọmọbinrin yii ti kuro lọọdẹ ọkọ ẹ, Abiọdun tipẹ, nigba ti ija de laarin wọn, ti wọn o si ri ọrọ naa yanju, ati pe nigba to ya, to lọọ fẹ ọkọ mi-in, lo yọnda ọmọbinrin naa fun baba ẹ, ki wọn jọ maa ko o pa a, ko si siyawo mi-in lọọdẹ baba yii, oun atọmọ ẹ yii naa ni wọn jọ n sun ti wọn jọ n ji ninu yara kan to haaya ni Mowe, n loorun ba da wọn pọ, toyun fi de.

Ṣa, CP Frank Mba, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ ki wọn taari afurasi ọdaran yii, Abiọdun Ọladapọ, si ẹka ti wọn ti n tanna wodi iwa ọdaran abẹlẹ lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweẹran, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, iwadii to lọọrin si ti n tẹsiwaju.

Lẹyin iwadii, gbogbo awọn ti aje iwa ainitiju yii ba ṣi mọ lori ni wọn yoo fimu kata ofin ni kootu, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply