Eemọ ree o, baba agbalagba fun ọmọọmọ ẹ loyun l’Ado-Odo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọwọ ọlọpaa teṣan Ado-Odo ti tẹ baba agba ẹni aadọrin ọdun (70) kan, Hunsu Sunday, ẹni to ba ọmọọọmọ rẹ obinrin ti ko ju ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lọ lo pọ,  to si fun un loyun.

Ẹẹkan kọ ni baba agba ṣe ‘kinni’ naa gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣe sọ. O ni latigba ti iya ọmọbinrin naa ti ku lo ti n gbe lọdọ baba-baba rẹ yii l’Ado-Odo, afi bi baba ṣe bẹrẹ si i ba a sun, to si ṣe bẹẹ fun un loyun.

Ọmọ to loyun paapaa ko mọ pe oyun ni, nigba to bẹrẹ si i ri awọn apẹẹrẹ oyun lara rẹ ti ko si ye e lo sọ bo ṣe n ṣe e fun aunti rẹ kan. Nigba naa lo jẹwọ fun aunti yii pe baba to bi baba oun ti n ba oun sun, o ti ṣe diẹ, ati pe lẹnu ọjọ mẹta yii loun ti n ri awọn apẹẹrẹ kan ti ko ye oun ninu ara oun.

Aunti to mọ itumọ ohun to ṣẹlẹ naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ado-Odo, ti DPO Micheal Arowojẹun fi ran awọn ikọ rẹ lati lọọ mu baba to jẹ eewọ naa wa.

Bi wọn ti mu Alagba Hunsu de teṣan ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo lo jẹwọ pe loootọ ni, o loun ti n ba ọmọọmọ oun naa sun fungba diẹ, ṣugbọn oun ko mọ pe o loyun rara.

Ṣa, wọn ti mu ọmọdebinrin naa lọ sọsibitu fun itọju, wọn si ti gbe baba agba naa lọ sẹka to n gbọ ẹjọ awọn to ba ṣe ọmọde niṣekuṣe gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ.

 

Leave a Reply