Ọkunrin kan to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga pata ni ileefowopamọ apapọ ilẹ wa (Central Bank of Nigieria), Ọmọwe Obadiah Mailafiya, tun tẹnu mọ ọn lanaa pe gomina ilẹ Hausa kan to wa lori aga ijọba lọwọlọwọ bayii ni olori pata fun awọn Boko Haram. O ni nibi ti ọrọ de bayii, ki a ma jẹ ki ẹnikẹni pe aja ni ọbọ fun wa mọ o, ki gbogbo ọmọ Naijiria mọ pe gomina yii lo wa nidii aburu to n ba wọn.
Ọjọ Aje, Mọnde ijẹrin, ni ọkunrin naa ti kọko sọrọ yii lori eto redio kan, to ni lara awọn ti wọn ṣẹṣẹ ronu piwada ninu awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo Boko Haram yii sọ foun pe gomina naa ni olori awọn kaafata, ko si si ohun kan to n lọ to ṣẹyin ọkunrin gomina naa. Bi Mailafiya ti sọ bayii lawọn agbofinro DSS ranṣẹ si i, wọn ni ko waa ṣalaye ohun to mu un sọ bẹẹ. Ni wọn ba mu un lọ si agọ wọn to wa ni Kuba Road niluu Jos lanaa. Ṣugbọn wọn fi i silẹ nigbẹyin, bo si ti jade lo tun tẹnu mọ ọn pe oun ko le ko ọrọ oun jẹ, nitori ootọ pọnnbele ni.
O jọ pe wọn ni ko bọ si gbangba ko ni oun ko sọ bẹẹ mọ ni, ṣugbọn Mailafiya loun ko ni i sọ bẹẹ, nitori ododo to fidi mulẹ ni ohun ti oun sọ. Awọn gomina ilẹ Hausa paapaa tilẹ ti kin Mailafiya lẹyin, wọn ni ki ẹnikẹni ma tori ọrọ to sọ yii pa ohùn mọ agogo rẹ lẹnu o, kaka bẹẹ, ki wọn jẹ ko wi tẹnu ẹ, ki ijọba si gbe iwadii to rinlẹ dide lori ọrọ naa, ki wọn le mọ eyi ti i ṣe ododo.