Eeyan bii ogun lọkọ tẹ pa ninu ọja Ibaka, l’Akungba-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

O kere tan, eeyan bii ogun la gbọ pe wọn ku, nigba tawọn mi-in tun fara pa ninu ijamba ọkọ to waye laarin ọja Ibaka, niluu Akungba Akoko, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide.

Alaye ta a gbọ lati ẹnu ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ naa ni pe awakọ ajagbe kan to n bọ lati ọna ilu Ikarẹ Akoko lo padanu ijanu ọkọ rẹ lojiji nigba to n sọkalẹ lati ori Okerigbo, eyi ti ko fi bẹẹ jinna rara si Fasiti Adekunle Ajasin, to wa niluu Akungba.

Loju ẹsẹ lo ni ọkọ tirela to ko ọpọ irẹsi ọhun ti tẹ awọn eeyan bii ogun pa, bẹẹ lo tun ṣe ọgọọrọ awọn ara ọja ọhun atawọn eeyan mi-in leṣe yannayanna.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ni ijamba ọhun waye.

O ni awọn eeyan bii mẹjọ loun gbọ pe wọn ku sinu ijamba ọkọ naa, ati pe o ṣee ṣe kawọn oku ti wọn ko ti i ri fa yọ ṣi wa labẹ tirela to subu ọhun.

Leave a Reply