Eeyan kan jona ku ninu ijamba ọkọ ni Bode-Saadu si Jẹbba

Stephen Ajagbe, Ilorin

Eeyan kan padanu ẹmi rẹ, ti ọkọ tirela marun-un si jona raurau ninu ijamba to ṣẹlẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, lagbegbe Ọlọla, lọna Bode-Saadu si Jẹbba, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mẹjọ aarọ niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ laarin ọkọ agbepo bẹntiroolu ati akẹru to lọọ fori sọra. Eeyan kan ṣoṣo to ku nibi ijamba naa jona kọja idamọ.

Alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ loju popo, FRSC, Ọgbẹni Azeez Ọlaolu, lo fi iṣẹlẹ naa to ajọ panapana leti.

O ni awọn oṣiṣẹ panapana sare lọ sibẹ lati doola ẹmi awọn to wa ninu ọkọ naa ati dukia wọn. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ẹni kan ti jona ku.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọga agba ajọ FRSC, ẹka tipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Ọwọade, ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ijanu ọkan lara awọn ọkọ naa lo daṣẹ silẹ loju ere, eyi gan-an lo fa ijamba naa.

Ọwọade sọ pe eeyan mẹrin lo wa ninu ijamba naa, ṣugbọn awọn mẹta lo mori bọ lai ni ifarapa kankan.

O ni awọn ti ko awọn ọkọ naa si ikawọ ileeṣẹ ọlọpaa. O gba awọn awakọ nimọran lati maa ṣọra loju popo, ki wọn si ṣọra fun ere asapajude, nitori pe ẹni ba gunlẹ layọ lawọn eeyan maa pe ni awakọ to dara ju lọ.

 

 

 

 

Leave a Reply