Eeyan kan ku lasiko ti bọọsi kan lari mọ tirela to duro jẹẹjẹ ni marosẹ Eko s’Ibadan

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ni nnkan bii aago kan aabọ geerege ọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsan-an yii, ni ọkọ akero kan lọọ lari mọ tirela to duro tiẹ jẹẹjẹ lagbegbe afara Iṣara, ni marosẹ Eko s’Ibadan, bi ọkunrin kan se dagbere faye ninu awọn marun-un to wa ninu bọọsi naa nìyẹn.  Alukoro TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, to fi iṣẹlẹ yii lede l’Abẹokuta, salaye pe awakọ bọọsi ti nọmba ẹ jẹ LND 631 XX lo n wa iwakuwa. O ni ere buruku ni dẹrẹba naa n sa, eyi lo fa a to fi kọlu tirela ti nọmba tiẹ jẹ KTU. 608 XW, nibi tiyẹn duro ẹ si jẹẹjẹ.  Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni ọkan ninu awọn marun-un to wa ninu bọọsi naa ku loju-ẹsẹ, awọn mẹrin yooku ti dẹrẹba naa wa lara wọn si fara pa.  Mọṣuari ileewosan Ọlabisi Ọnabanjọ (OOUTH) to wa ni Ṣagamu, ni wọn gbe oku ẹni to doloogbe naa lọ gẹgẹ bi Akinbiyi ṣe wi. Ẹka itọju ni wọn si gbe awọn mẹrin to fara pa lọ.

Leave a Reply