Eeyan kan ku lẹyin to jẹun nibi ayẹyẹ isọmọlorukọ n’Iragbiji

Florence Babaṣọla

Wahala nla lawọn araalu Iragbiji atawọn arinrin-ajo ti wọn ni lati gba oju-ọna Ikirun si Ada kọja koju l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, latari bi awọn kan tinu n bi ṣe di awọn ọna naa, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni raaye kọja.

Ṣe la gbọ pe awọn eeyan naa n fẹhonu han lori ọrẹ wọn kan ti wọn lo ku lẹyin to jẹ ounjẹ isọmọlorukọ tan.

Titipa ni gbogbo awọn ṣọọbu, ileewe, ileetaja, ileejọsin wa, bẹẹ lawọn ọdọ naa n ko ada, afọku igo, igi kaakiri, ti wọn si dana si ẹnu-ọna abawọle si aafin Aragbiji, orita Alabiamọ, ati orita Popo.

Ṣe ni awọn onimọto ti ọna wọn jẹ mọ Ikirun/Iragbiji/Ada n gba ọna mi-in lati le bọ lọwọ wahala awọn olufẹhonu han ọhun fun ọpọlọpọ wakati ti wọn fi pitu ọwọ wọn.

Ọkunrin kan to n gbe ninu ilu Iragbiji, Kamọrudeen, ni lọjọ Tusidee ọsẹ yii ni ẹnikan pe oloogbe ọhun lọ sibi isọmọlorukọ kan ti wọn ṣe lorita Alabiamọ, niluu naa.

Kamọrudeen ṣalaye pe bi ọmọkunrin naa ṣe jẹun tan lo ti bẹrẹ si i lọnu mọlẹ, to si pada gbabẹ ku.

O ni igbagbọ awọn ọrẹ ọmọkunrin yii ni pe ṣe ni wọn fun un ni majele jẹ nibi ayẹyẹ isọmọlorukọ naa, idi si niyẹn ti wọn fi pinnu lati fẹhonu han kaakiri ilu.

Ṣugbọn nigba ti a ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni awọn ọdọ tinu n bi lori bi awọn ọlọpaa ṣe fi pampẹ mu awọn kan lara wọn ni wọn n fẹhonu han.

Ọpalọla ṣalaye pe lori ẹsun lilo ati tita oogun oloro (drug related offences) lawọn ọlọpaa mu awọn ọdọ naa fun, idi si niyẹn ti awọn ẹgbẹ wọn fi n dana sun taya kaakiri, ṣugbọn o ni alaafia ti pada sagbegbe naa bayii.

Leave a Reply