Florence Babaṣọla
Eeyan kan lo ti ku bayii, nigba ti awọn mẹta mi-in fara pa nibi wahala kan to ṣẹlẹ laarin awọn ẹya Hausa ati Yoruba ti wọn n gbe lagbegbe Sabo, niluu Oṣogbo.
Titi digba ti a n kọroyin yii, ṣe ni gbogbo ile ati ṣọọbu wa ni titi pa lagbegbe naa, pẹlu ibẹru si lawọn eeyan fi duro ninu ile, bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ti wa nibẹ.
Alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe wahala naa bẹrẹ. Awọn ọdọ kan ni won kora wọn jọ, wọn ni awọn n ṣe idaro ikẹyin (candle night) fun ọkan lara awọn to jade laye laipẹ yii.
Lasiko yii ni itaporogan bẹrẹ laarin wọn pẹlu awọn ti wọn n taja nibẹ, wọn si ṣe ọmọ Hausa kan lese, ti ọpọ si fara pa.
Bo tun ṣe di aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn ọmọọta tun ya lọ sagbegbe Sabo, Ahmadiyah ati Abaku, ti wọn si n doju ija kọ gbogbo awọn ti wọn ri nibẹ pẹlu ibọn atawọn nnkan ija mi-in.
Nibẹ nibọn ti ba Hausa kan, ti gbogbo agbegbe naa si gbona janjan.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ọlọpaa ti wa nibẹ lati ṣeto aabo, bẹẹ lo ni oun ko ti i le sọ nnkan to fa wahala naa.