Eeyan marun-un ku ni marosẹ Eko s’Ibadan, ere asapajude lo fa a

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹsan-aabọ aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, leeyan marun-un (ọkunrin meji, obinrin mẹta), doloogbe lagbegbe Inter-Change, iyẹn loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, nigba ti awọn mọto mẹta kọlu ara wọn.

Awọn mọto ọhun gẹgẹ bi Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe sọ f’ALAROYE ni :Mazda kan to jẹ bọọsi akero, tanka kan ati tirela.

O ṣalaye pe ọkọ bọọsi ti nọmba ẹ jẹ GGE 296 DC lo n sare asapajude, to fẹẹ ya awọn yooku silẹ, nibi ti ijamba ti waye niyẹn.

Ibadan ni bọọsi akero yii n lọ, bẹẹ naa si ni ọkọ tanka keji. Nibi to ti fẹẹ ya tirela to wa niwaju ẹ lo ti lari mọ ọkọ mi-in to n bọ lati Ibadan. Tanka naa gba a sabẹ tirela ko too ti i wọnu igbo, nigba ti wọn yoo si fi wo awọn eeyan to wa nibẹ, marun-un ti ku ninu awọn mẹjọ.

Awakọ to wa tanka naa sa lọ ni tiẹ nigba to ri ohun to ṣẹlẹ, eyi to wa tirela wa lọsibitu Idẹra, ni Ṣagamu, to n gbatọju lọwọ, bẹẹ ni wọn gbe oku awọn to doloogbe naa lọ si mọṣuari ọsibitu kan naa.

Bi ajọ TRACE ṣe ba ẹbi awọn to doloogbe kẹdun, bẹẹ naa ni wọn n kilọ fawọn awakọ pe ki wọn yee sare loju popo, nitori ẹmi alaiṣẹ to n sọnu yii ṣe n pọ ju

Leave a Reply