Eeyan marun-un ku ninu ikọlu awọn Fulani ati agbẹ n’Imẹkọ

Adefunkẹ Adebiyi,  Abẹokuta

Ikọlu to maa n waye laarin awọn Fulani ati agbẹ nipinlẹ Ogun tun ti waye, ko si din leeyan marun-un to ba iṣẹlẹ naa lọ, bẹẹ ni wọn dana sunle atoko pẹlu ọkada ati maaluu l’Abule Idọfa, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn, nipinlẹ Ogun.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe awọn agbẹ to n dako lagbegbe Aworo, n’Imẹkọ, ni wọn le awọn Fulani kuro lagbegbe wọn. Wọn ni awọn Fulani n fi maaluu jẹko awọn, wọn si tun n ko ẹranko wọnu odo tawọn n mu. Gbogbo nnkan wọnyi si nijọba ipinlẹ Ogun ti fofin de.

Lasiko ti wọn le awọn Fulani naa de Idọfa ni wọn pa Fulani mẹta pẹlu awọn maaluu wọn.

Nigba to di l’Ọjọbọ, Tọsidee, ti i ṣe ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni yii, eyi ti ko ju wakati diẹ sasiko ti wọn le wọn kuro l’Aworo, awọn Fulani naa gbe ija de, wọn doju kọ Idọfa, wọn si paayan meji nibẹ, wọn dana sun ibi ti wọn n tọju agbado si mẹrin ati ọkada awọn eeyan kan.

Ọkan ninu awọn ti wọn pa yii jona mọle raurau ni ba a ṣe gbọ, ile tawọn Fulani dana sun loun wa ninu ẹ, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ati Amọtẹkun ti wọn debẹ lati yanju ẹ. Yoruba ni wọn pe awọn meji to doloogbe n’Idọfa yii.

Koda titi dasiko yii ni awọn Ọhọri ti wọn n ṣiṣẹ agbẹ n’Idọfa ṣi n gbatọju latari ijamba to ṣe wọn, awọn mi-in si ti sa kuro nile ninu awọn olugbe ilu naa bayii, ibẹru ohun to tun le ṣẹlẹ lo mu wọn.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Ogun fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ lo waye. Oyeyẹmi sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ko ti i mu afurasi kankan.

O fi kun un pe aabo ti lagbara si i lawọn agbegbe yii, ohun to si daju ni pe ọwọ yoo ba awọn to lọwọ ninu ikọlu to fi ẹmi eeyan ati ọpọlọpọ dukia ṣofo yii.

 

Leave a Reply