Eeyan marun-un tun ku ni Kara, nigba ti bọọsi fori sọ tirela

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 Ko din leeyan marun-un to tun dagbere faye lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii, iyẹn ni Kara, lori afara marosẹ Eko s’Ibadan.

Gẹgẹ bi ọga FRSC nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ahmed Umar ṣe ṣalaye, o ni bọọsi Mazda ti nọmba ẹ jẹ EPE 575 XA, ni dẹrẹba rẹ n wa iwakuwa. O ni ere naa pọ debii pe o padanu ijanu rẹ, bo ṣe lọọ kọ lu tirela to n yipada lọwọ ẹyin niyẹn. APP 397 YA, ni nọmba tirela naa gẹgẹ bi Ahmed ṣe wi.

Awọn to ku ninu ijamba naa
Awọn to ku ninu ijamba naa

Ẹsẹkẹsẹ ti dẹrẹba yii kọ lu tirela ni wahala de, obinrin mẹrin ati ọkunrin kan lo ku loju ẹsẹ, eeyan mẹrinla si farapa.

 Ileewosan Jẹnẹra Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu ni wọn gbe awọn to fara pa lọ, nigba ti wọn gbe oku marun-un lọ si mọṣuari Fakọya, ni Ṣagamu, kan naa.

Leave a Reply