Eeyan mẹrin padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ ni Mọniya

Ọlawale Ajao, Ibadan

Eeyan mẹrin lo ku loju-ẹsẹ ninu ijamba ọkọ kan to waye ni Mọniya, n’Ibadan, ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Nibi ti ọkọ tasin micra kan to n na Sango si Mọniya ti n gbiyanju lati ya ọkọ tirela to wa niwaju ẹ ṣilẹ laduugbo ti wọn n pe ni Funduck, ni Mọniya, nijamba ọhun ti waye, nigba ti ọkọ tasin naa lọọ fori sọ tirela mi-in to n bọ latọna Ijaye wa sigboro Ibadan.

Ọgbẹni Fẹmi Ilọri tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe afọwọfa awakọ tasin ọhun lo ṣokunfa ijamba ọhun, o ni ainisuuru lo ko ba a.

“Nibi ti gálọ́ọ̀bù wa, to jẹ pe gbogbo ọkọ to n lọ ati eyi to n bọ ni wọn maa n du apa ibi to daa ni onimicra yẹn ti fẹẹ ofatéèkì tirela, o ro pe tirela yẹn maa ni suuru fun oun ni, sugbọn iyẹn ko ni suuru fun un rara. Bo ṣe lọọ kọ lu ọkọ mi-in to bọ niwaju niyẹn.

“Eeyan mẹrin lo ku loju-ẹsẹ, ẹni karun-un ko ku, ṣugbọn o fara pa gan-an.”

ALAROYE gbọ pe awọn oṣiṣẹ FRSC, iyẹn ajọ to n ri si eto aabo loju popo ni wọn gbe ẹni ti ori ko yọ lọwọ iku oro yii lọ sileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si tọju awọn mẹrẹẹrin to padanu ẹmi wọn pamọ si yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan ọhun.

Leave a Reply