Eeyan mẹẹẹdogun bọ sọwọ ọlọpaa, nitori ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Ketu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Lẹyin rogbodiyan ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ni Ketu, nipinlẹ Eko, eeyan mẹẹẹdogun ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu bayii.

Ṣe laaarọ kutu hai ni wahala bẹ silẹ lọja eeso to wa ni Ketu, nigba ti wọn ni awọn ti wọn n gba owo tikẹẹti atawọn kan bẹrẹ si i ja lori owo.

Ija ọhun lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ba wọn da si, keeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti bẹrẹ si i ba dukia jẹ, wọn n dana sun ṣọọbu, dana sun ọja awọn eeyan, bẹẹ ni iro ibọn n dun lakọkọlakọ.

Awọn ọmo ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, Aye ati Bucanner ni wọn sọ ija naa di tiwọn, ninu wọn naa si ni eeyan mẹẹẹdogun tọwọ ba yii, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Olumuyiwa Adejọbi, ṣe sọ.

Adejọbi ṣalaye pe ibọn ilewọ ibile meji, awọn ọta ibọn ti wọn ko ti i yin, oogun abẹnugọngọ atawọn nnkan mi-in lawọn ri gba lọwọ awọn wọnyi, awọn si ti taari wọn si Panti, ni Yaba, nibi ti itẹsiwaju iwadii yoo ti waye si i lori ẹjọ naa.

Alaafia ti pada si agbegbe Ikosi-Ketu ti rogbodiyan naa ti waye gẹgẹ bi alukoro ṣe wi, bẹẹ ni wọn ti da awọn ọlọpaa sibẹ lati maa ṣọ ibẹ, ẹnikẹni to ba si rin irin ifura yoo bọ sọwọ, gẹgẹ bi wọn ṣe lawọn ṣi n wa awọn mi-in ti wọn tun lọwọ si rogbodiyan naa.

Leave a Reply