Eeyan mẹfa ku ninu ijamba ọkọ l’Ogere

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ko din leeyan mẹfa to padanu ẹmi wọn ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla yii, lagbegbe Ogere, iyẹn ni marosẹ Eko s’Ibadan, nigba ti tirela ati jiipu Honda Pilot fori sọ ara wọn.

Ọga FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, ṣalaye pe yatọ sawọn mẹfa to ku yii, ẹni kan tun fara pa gidi to si wa nileewosan bayii.

Umar fi kun alaye ẹ pe dẹrẹba to wa jiipu lo sare kọja alaafia. O ni mọto ti nọmba ẹ jẹ LSR 525 FY yii lo kọja aaye ẹ pẹlu ere buruku to n sa, bo ṣe lọọ ko si tirela to ni nọmba KRV 716 ZV to n lọ jẹẹjẹ ẹ labẹ nìyẹn.

 

Ọkunrin marun-un, obinrin kan, lawọn to doloogbe ninu ijamba naa bi ọga FRSC yii ṣe wi. Wọn ti ko wọn lọ si mọṣuari FOS, n’Ipara, wọn si gbe ẹni kan to ṣeṣe lọ si ọsibitu Idẹra, l’Ogere.

Leave a Reply