Eeyan mẹfa ku ninu ijamba ọkọ ni marosẹ Eko s’Abẹokuta, ọmọde meji wa ninu wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago meji ọsan kọja iṣẹju mẹwaa ni ijamba ọkọ kan ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Eko s’Abẹokuta, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii. Eeyan mẹfa lo ku, ninu eyi ti awọn ọmọde meji wa, eeyan mejila si tun fara pa.

Adari ẹṣọ oju popo FRSC, nipinlẹ Ogun, Kọmandanti Ahmed Umar ṣalaye pe lagbegbe Lala si Kere, niṣẹlẹ yii ti waye, ati pe mọto Mitsubishi kan ti nọmba ẹ jẹ  XS 595 JJJ lo fẹẹ yi ori pada lai wo bi iwaju ṣe ri, nigba naa ni Mazda ti nọmba tiẹ jẹ  LSR 266 YD lo kọ lu u, ti ijamba to fẹmi eeyan mẹfa ṣofo si waye.

O ni eeyan mejidinlogoji ni ijamba yii kan, ogun ọkunrin ati obinrin mẹtala ni wọn. Eeyan mejila ni Umar sọ pe wọn fara pa, ọkunrin mẹjọ, awọn agbalagba obinrin mẹta ati ọmọdebinrin kan.

Eeyan mẹfa lo doloogbe, baale ile mẹrin, ọmọdekunrin ati ọmọdebinrin kan.

Ileewosan jẹnẹra l’Abẹokuta ni wọn ko awọn to ṣeṣe lọ, mọṣuari ibẹ naa ni wọn ko oku awọn to doloogbe si.

Leave a Reply