Eeyan mẹfa ni Dosumu ti pa l’Ogere ati Ipẹru, ariwo oun fẹẹ mu ẹjẹ ni wọn lo n pa  

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu ibẹru ati ikayasoke lawọn eeyan Ogere ati Ipẹru-Rẹmọ, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ, nipinlẹ Ogun, wa. Ọmọkunrin kan to n ṣa wọn pa nibẹ, Feyiṣọla Dosumu, ti wọn n pe ni Spantra, lo tun ṣọṣẹ lọjọ Iṣẹgun to kọja yii, to ṣa eeyan meji ladaa pa.

Obinrin kan to n tọmọ lọwọ ni Feyiṣọla ṣa pa l’Ogere, ko too lọ s’Ipẹru, nibi to ti ṣa ọkunrin ọlọdẹ kan to n ṣọ ileeṣẹ ti wọn ti n sin adiẹ pa.

Spartan yii n mugbo gidi, o si jọ pe oogun oloro paapaa wa ninu ohun to n mu. Ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni nigba to wa nileewe gbogboniṣe MAPOLY, l’Abẹokuta, titi dasiko yii naa la si gbo pe ọga agba ni ninu ẹgbẹ okunkun to wa.

Ninu oṣu karun-un, ọdun yii, lo ṣa eeyan mẹrin pa lawọn agbegbe meji yii, bo si ṣe pitu ọhun to, awọn ọlọpaa ko ri i mu, o sa lọ bamu ni.

Baba kan wa ninu awọn to ṣa loṣu karun-un naa to jẹ Ọlọrun ni ko pa a. Ṣọọṣi ni baba naa n lọ n’Ipẹru, ọmọ ijọ Ridiimu ni. Ojiji ni ọmọ to n paayan yii da a lọna, o si bu u ladaa lori, o ṣa a yanna yanna. Niṣe lo ro pe Alagba naa ti ku nigba tiyẹn ti ṣubu lulẹ, ti ẹjẹ si ti bo o, nigba naa ni Spartan sa lọ. Ṣugbọn baba naa ko ti i ku, ẹmi ṣi wa lara rẹ nigba tawọn eeyan ri i ninu agbara ẹjẹ, wọn si gbe e lọ sọsibitu fun itọju.

Ẹnikan to jẹ ara ṣọọṣi baba yii sọ fun akọroyin wa pe idaji miliọnu Naira lawọn dokita sọ pe kawọn san lati ṣiṣẹ abẹ ori fun baba naa, ko le gbadun daadaa, ko si ma ni ipenija ọpọlọ lẹyin iṣẹlẹ naa.

 

Awọn eeyan ilu mejeeji yii ṣẹṣẹ n mọkan kuro ninu iṣẹlẹ igba naa ni Feyiṣọla tun yọ de wurẹ lọjọ Iṣẹgun, to si tun ṣe bẹẹ paayan meji ti ko ṣẹ ẹ lẹṣẹ kankan.

 

Loootọ ni wọn ni ori Feyiṣọla ko pe mọ, a gbọ pe imukumu to n mu ti yi i lori, ati pe ileewosan ti wọn ti n tọju awọn alarun ọpọlọ l’Abẹokuta lo ti n gba itọju ko too sa kuro nibẹ. Ṣugbọn bo ṣe n ṣiwere to yii, ohun ti wọn lo maa n sọ ni pe ẹjẹ n wu oun i mu, ongbẹ ẹjẹ n gbẹ oun, oun yoo si mu un. To ba ti n wi bẹẹ naa ni yoo wọle tọ awọn ẹni ẹlẹni lọ, ti yoo ṣa wọn pa.

Ko too lọọ pa awọn meji yii, ile adiẹ to ti paayan yii ni wọn lo kọkọ lọ pẹlu ada lọwọ lọsẹ meji sẹyin, o si bẹrẹ si i ṣa awọn adiẹ ladaa, o pa to ọgọrun-un kan (100) adiẹ ki wọn too kapa ẹ, ti wọn si le e jade nibẹ. Afi bo ṣe tun gbabẹ lọ ni Tusidee to kọja yii, to si ṣa ọdẹ to n ṣọ ibẹ pa.

ALAROYE gbọ pe Feyiṣọla n leri kiri pe oun yoo ṣi paayan si i lawọn ilu yii, eyi lo si fa ikayasoke fawọn olugbe ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ to ti n ṣọṣẹ naa bayii, to jẹ oju kan ni wọn fi n sun, wọn ko le fẹdọ lori oronro.

Ipẹru-Rẹmọ yii ni ilu Gomina Dapọ Abiọdun, ibẹ naa lo n gbe pẹlu idile rẹ, ṣugbọn ifọkanbalẹ ko si nibẹ bayii, latari Spartan to n ṣa wọn pa. Nitori iṣẹlẹ yii naa ni CP Edward Awolọwọ Ajogun ṣe lọ si Ipẹru ati Ogere laarin ọsẹ naa, to si di pe wọn da awọn ọlọpaa sita pẹlu awọn fijilante ati awọn ẹṣọ kan ti wọn n pe ni ‘Neighbourhood watch’, ṣugbọn bakan naa lọmọ ṣori, wọn ko ti i ri i titi ta a fi pari iroyin yii.

Ṣugbọn Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti sọ pe bi aja ba lo ogun ọdun laye, ẹran Ogun ni. O ni bi Feyiṣọla sa pamọ ju bẹẹ lọ, ọwọ awọn yoo ba a laipẹ, nitori awọn n wa a gidi, awọn si ti kede ẹ pe ẹni tijọba n wa ni.

Oyeyẹmi ni ko sọgbọn ki Spartan ma jiya bọwọ ba tẹ ẹ, niori awọn ti n wa a lati jiya ipaniyan to n tọwọ rẹ waye kiri.

O kere tan, eeyan mẹfa lo ti doku latọwọ Feyiṣọla, apaayan to n ṣa wọn pa l’Ogere ati Ipẹru-Rẹmọ.

One thought on “Eeyan mẹfa ni Dosumu ti pa l’Ogere ati Ipẹru, ariwo oun fẹẹ mu ẹjẹ ni wọn lo n pa  

  1. Ryan to payan Kiri tiwon sope won fe iru eyan toti yawere tiwon sope kiwon mu nse loye ki won yibon pa ohun naa ni toripe tiwon ban kiwon mareti atimu olesebe kotun pa elemiran ki ilese olopa pase wipe kiwon yibon Pa tiwon bati fi oju kan lesekese.

Leave a Reply