Eeyan mẹfa padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ epo bẹntiroolu to gbina niluu Jẹbba

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn, ti ọpọlọpọ dukia ṣofo laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nibi ijamba ọkọ epo bẹntiroolu to ṣẹlẹ niluu Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe gbugburu lawọn eeyan jona nibi iṣẹlẹ ọhun, ti awọn ile ati ṣọọbu bii ọgbọn si ba a lọ pẹlu ọja inu ẹ.

Lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe lasiko ti ọkọ epo naa n gba igboro ilu Jẹbba kọja lo lọọ ya wọ ile tawọn eeyan wa, to si fọn bẹntiroolu si gbogbo adugbo naa, ki awọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ina buruku ti ṣọ.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, ti ba mọlẹbi awọn to padanu ẹmi ati dukia wọn nibi ijamba naa kẹdun, o ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bii eyi to ba ni lọkan jẹ gidi.

Atẹjade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, ni ijọba ti n gbe igbesẹ lati mọ bi adanu naa ṣe to ati ọna lati ran awọn to fara gba ijamba naa lọwọ.

“Gomina ti ran ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kwara, State Emergency Management Agency (SEMA), lọ sibẹ lati ba ẹbi awọn to ku kẹdun, ati lati mọ ọna tijọba fi le ran awọn to padanu dukia wọn lọwọ.”

Leave a Reply