Eeyan meje foju bale-ẹjọ lori ija awọn Musulumi ati Eleegun l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olori ijọ Kamorudeen Society Central Mosque, Qosim Yunus, ati mẹta lara awọn ọmọ ijọ rẹ pẹlu awọn eleegun mẹta ni wọn ti n kawọ pọnyin rojọ ni kootu Majisreeti kan niluu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lori wahala to waye laarin wọn laipẹ yii.

Ẹsun ti agbẹjọro to wa lati ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Badiora, fi kan Yunus atawọn ọmọ ijọ rẹ; Salawu Jimoh, Alarape Sulaiman ati Raimi Saheed ni pe wọn huwa to le da omi alaafia agbegbe ru, didi ọlọpaa lọwọ lati ṣiṣẹ, didoju ija kọ eeyan ati didoju ija kọ inspẹkitọ ọlọpaa obinrin kan.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Badiora sọ pe wọn huwa naa ni adugbo Oluọdẹ Aranyin, Oṣogbo, ninu eyi ti aafa kan ti ku, ti awọn mẹrinla si fara pa yanna-yanna.

Bakan naa ni Badiora fẹsun mẹrin kan Ifashọla Eṣuleke, Adeọṣun Kọla ati Idowu Abimbọla. O ni wọn ba dukia jẹ, wọn ba mọṣalaaṣi kan jẹ, bẹẹ ni wọn si ba mọto Toyota Camry kan to ni nọmba GGE 954 BV jẹ nibi iṣẹlẹ naa.

Badiora sọ siwaju pe awọn ẹsun naa ni ijiya nla labẹ abala ikẹtalelọgọrin, igba o din mẹta, ọtalelọọọdunrun o din marun-un, okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹta ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.

Agbẹjọro awọn Musulumi, Kazeem Babatunde ati ti awọn eleegun, Abimbọla Ige, bẹbẹ fun beeli awọn olujẹjọ lọna irọrun pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa fun igbẹjọ.

Onidaajọ Asimiyu Adebayọ faaye silẹ fun beeli ọkọọkan awọn olujẹjọ pẹlu miliọnu kan naira ati oniduuro kọọkan ni iye kan naa. O ni awọn oniduuro ọhun gbọdọ ni ilẹ to jẹ tiwọn.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Leave a Reply