Eeyan meje jona ku nibi ijamba ọkọ l’Ogunmakin

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko din leeyan meje ti wọn jona ku raurau lalẹ ojọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla yii, awọn mẹta mi-in si fara kona rẹpẹtẹ bo tilẹ jẹ pe wọn ko ku, iyẹn ninu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ lagbegbe Sandrete, nitosi Ogunmakin, loju ọna marosẹ Eko s’ibadan

Nnkan bii aago mọkanla ku ogun iṣẹju ni ijamba yii ṣẹlẹ, gẹgẹ bi oga FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, ṣe sọ.

O ni ọkọ bọọsi ati tirela ni ọrọ ọhun kan, awọn mejeeji ni ko si ni nọmba idanimọ.

Nigba to n ṣalaye lori bi ijamba ina ṣe waye, ọga FRSC naa sọ pe awọn ọkọ mejeeji fori sọ ara wọn ni, nibi ti wọn ti n gba ọna ti ko yẹ ki wọn gba. O ni bi wọn ṣe fori sọ ara wọn naa lo fa a ti ina fi ṣẹ yọ, to si jo eeyan meje pa raurau kọja idanimọ. O ni agbari wọn lasan lo ṣẹku silẹ.

Awọn mẹta mi-in naa fara kona gẹgẹ bi Ahmed ṣe wi, ọṣẹ naa ṣe wọn to jẹ wọn gbe wọn lọ sileewosan Victory Hospital, l’Ogere ni.

Ọga FRSC yii gba awọn awakọ nimọran pe ki wọn yee gba ọna ti ki i ba ṣe tiwọn, ki wọn yee sare loju popo, ki wọn si maa tẹle ofin irinna gbogbo.

O ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun, o si ni ki wọn lọ si ileeṣẹ ẹṣọ alaabo oju popo, FRSC, to wa l’Ogunmakin, fun ẹkunrẹrẹ alaye nipa iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply