Eeyan meje ku, mewaa farapa yanna-yanna, nibi ile to wo l’Ekoo

Eeyan meje ni iku ojiji pa ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii nigba ti ile oloke mẹta kan da wo ni agbagbe Ọbalende, l’Ekoo, ti eeyan mẹwaa mi-in si farapa yannayanna.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Odo, ni Ojule ọgọta (60) ni ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye ni deede aago mẹfa ku ogun iṣeju, ti odidi ile oloke mẹta si wo lulẹ.

Wọn ni pupọ ninu awọn to n ṣiṣẹ ninu ile ti wọn n kọ lọwọ yii ni wọn ba iṣẹlẹ ọhun lọ. Musulumi ni wọn pe awọn kan ninu wọn, ati pe lasiko ti wọn n kirun lọwọ gan-an ni ile naa da wo lulẹ.

̀Ọga agba fun ileeṣẹ pajawiri l’Ekoo, Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ati pe awọn to fara pa ninu ẹ ti wa ni ọsibitu bayii nibi ti wọn ti gba itọju.

A gbọ pe ṣaaju asiko yii ni ijọba ti sọ pe ki wọn dawọ iṣẹ duro lori ile ti wọn n kọ yii nigba ti ijọba kiyesi pe ohun ti wọn n ṣe nibẹ ko bofin mu.

Paanu ti won fi n ṣe orule ni wọn sọ pe wọn fi ṣe ọgba, eyi ti wọn fi yi ile naa ka, ti wọn si n dọgbọn kọ ile naa lọ, ko too di pe gbogbo ẹ wo lulẹ lọjọ Aiku, Sannde, to si ṣe ẹmi awọn eeyan lofo rẹpẹtẹ.

Ohun tawọn eeyan tun sọ ni pe o ṣee ṣe ki awọn ẹlomi-in ṣi wa ninu awoku ile naa. Eeyan mẹwaa lo fara pa rẹpẹtẹ, nigba ti awọn mẹwaa mi-in fara pa diẹ, ti eeyan meje si ti ku bayii.

 

Leave a Reply