Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bii ere ni kinni ọhun bẹrẹ n’Ibeṣe, nijọba ibilẹ Yewa, nipinlẹ Ogun, iyẹn ede aiyede to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii, laarin awọn ọlọkada atawọn yuniọnu to n ja tikẹẹti fun wọn, to si pada waa di ija ẹlẹyamẹya laarin Hausa ọlọkada atawọn Yoruba, eeyan meje si ṣe bẹẹ dagbare faye.
Ohun ti awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn sọ fun wa ni pe awọn yuniọnu to n ja tikẹẹti fawọn ọlọkada to wa nitosi ileeṣẹ simẹnti Dangote, n’Ibeṣe, fowo kun iye tawọn ọlọkada naa maa n ja tikẹẹti ọhun tẹlẹ.
Ẹgbẹta naira (600) ni wọn n ja tikẹẹti naa fun wọn tẹlẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, afi bo ṣe di laaarọ ọjọ naa ti wọn ni tikẹẹti ti di ẹgbẹrin naira(800).
Afikun yii lo bi awọn ọlọkada naa ninu, wọn si kọ, wọn lawọn ko ni i sanwo tuntun naa, iye tawọn n san tẹlẹ naa lawọn yoo maa san lọ.
Ọrọ naa dija, o di pe wọn ko le ṣiṣẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun yii, wọn ko si ri i yanju. Ṣugbọn lojiji lo di pe awọn ọlọkada yii tun kọju ija sira wọn, ẹya Hausa si pọ ninu awọn ọlọkada naa, wọn n ṣiṣẹ laarin awọn Yoruba ti wọn jẹ ọmọ ilu.
Bo ṣe di ohun ti wọn doju ija kọra wọn ko tete ye awọn eeyan, afi nigba to di pe Hausa n gbeja Hausa, ti awọn Yoruba naa n gbe sẹyin ara wọn.
Ko pẹ to fi di ohun ti oku bẹrẹ si i sun, nitori ija naa lagbara pupọ, niṣe ni wọn si pada se ọna ibẹ pa lati dẹkun awọn onija naa.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko din leeyan meje ti wọn ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko ti i le sọ iye ẹni to ku.
Oyeyẹmi sọ pe afikun to de ba owo tikẹẹti loun gbọ pe o dija silẹ, bo ṣe dohun ti Hausa ati Yoruba ti wọn jọ n ṣiṣẹ pọ tun n kọ lu ara wọn ko ye oun.
O lawọn ti kapa iṣẹlẹ yii ṣa, alaafia si ti jọba, nitori awọn ọlọpaa ṣi wa nibẹ, ti wọn n ṣọ agbegbe naa lati gbegi dina ikọlu mi-in to tun le fẹẹ waye.
Ṣugbọn awọn kan sọ pe iṣẹlẹ yii ki i ṣe nitori afikun owo tikẹẹti, wọn ni ọkan lara awọn to n wa tirela Dangote lo ṣeeṣi gba Hausa ọlọkada kan to duro nikorita Ibeṣe, oun si jẹ Yoruba, ni awọn Hausa ọlọkada ba binu tori eyi, o si di wahala.
Koda, awọn ṣọja waa da si ija naa lati pẹtu si i ba a ṣe gbọ, ṣugbọn niṣe lo jọ pe wọn tun da kun un, nitori a gbọ pe wọn ṣatilẹyin fawọn Hausa to n binu naa ni.
Yatọ sawọn to ti ku, awọn meji mi-in ti wọn pe orukọ wọn ni Ọdẹdẹ Najim ati Mulero Suleiman ba ara wọn lọsibitu ni.