Eeyan meje lo ku, wọn tun dan sun ọpọlọpọ ile ninu wahala Ilobu ati Ẹrin-Ọṣun

Florence Babaṣọla

Lasiko ti a n koroyin yii jọ, o kere tan, eeyan meje lo ti ba wahala ilẹ to ṣẹlẹ laarin ilu Ilobu ati Ẹrin Ọṣun, nipinlẹ Ọṣun, lọ, nigba ti wọn dana sun ile bii ọgọfa.

Lọjọ Satide to kọja ni wahala naa bẹrẹ lasiko ti awọn oṣiṣẹ ti wọn n ka iye ile to wa lagbegbe kọọkan (National Population Commission) n ṣeto aala ilẹ lagbegbe Ahoro Aafin.

Bi awọn eeyan ilu Ilobu ṣe n sọ pe awọn lawọn ni ilẹ naa, lawọn eeyan Ẹrin-Ọṣun n sọ pe ko sẹni to le gba a lọwọ awọn. Kekere lawọn eeyan kọkọ pe ọrọ naa, ṣugbọn lojiji lo di eyi ti wọn n yọbọn sira wọn.

Lati le dẹkun wahala naa, ijọba ipinlẹ Ọṣun kede konilegbele nijọba ibilẹ Irẹpọdun ati Orolu, sibẹ, wahala naa ko dawọ duro.

Oloye Inurin ti ilu Ẹrin Ọṣun, Ọlawuyi Adeleke ṣalaye fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe yatọ si eeyan mẹrin ti wọn ti ku lasiko wahala naa niluu Ẹrin Ọṣun, wọn dana sun ile to to ogun, bẹẹ ni wọn si dana sun mọto to le ni mẹwaa.

Loootọ ni alaafia ti pada sagbegbe naa bayii, gẹgẹ bi Oloye Adeleke ṣe sọ, sibẹ, inu ibẹrubojo lawọn araalu wa, ti wọn si n pariwo pe kijọba ko ọpọlọpọ awọn agbofinro lọ sibẹ.

Bakan naa ni Ọtun Jagun ti ilu Ilobu, Oloye Agba Goke Ogunṣọla, ẹni to tun jẹ oluranlọwọ fun ilu naa lori ọrọ ofin sọ ni tiẹ pe eeyan mẹta niluu naa ti padanu, nigba ti wọn dana sun ile to to ọgọrun-un.

O ni awọn eeyan ilu Ẹrin Ọṣun ni wọn ya wọlu Ilobu tibọntibọn lọsan-an ọjọ naa, o ni wọn ṣe awọn eeyan ilu naa ti wọn n bọ lati abule Aro ati Ara lese lọjọ yii.

Ninu ọrọ tiẹ, kọmiṣanna fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, sọ pe awọn agbofinro ko sinmi, bẹẹ ni wọn ko ṣaarẹ lọsan-an-loru lati da alaafia pada saarin ilu mejeeji.

Ọlọkọde fi kun ọrọ rẹ pe oku kan tawọn agbofinro ri loju ọna ni wọn ti gbe lọ sile igbokuu-pamọ-si ati pe ẹnikẹni ti ajere rogbodoyan naa ba ṣi mọ lori ki yoo lọ lai jiya.

Leave a Reply