Eeyan meje padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ lọna Ilọrin s’Ibadan

Ibrahim Alagunmu

O kere tan, eeyan meje lo ṣe kongẹ ọlọjọ wọn lasikoi ijamba ọkọ to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii,  lagbegbe ilu Ayekalẹ, lopopona marosẹ Ilọrin si Ibadan.

Ninu atẹjade kan ti adari ẹsọ alaabo oju popo nipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, fi lede niluu Ilọrin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti sọ pe owurọ kutukutu niṣẹlẹ naa waye, nigba ti ọkọ akero Toyota Bumper kan to ni nọmba ZAR600XY, sare asapajude, to si takiti pọnla-pọnla. Eeyan mọkandinlogun lo fara kaasa nibi ijamba ọkọ naa, ti eeyan meje si ku loju ina, awọn mejila fara pa yanna yanna. O tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa agọ Bode Saadu, nijọba ibilẹ Moro, ni wọn doola ẹmi awọn to fara pa naa, wọn ko wọn lọ si ileewosan to sun mọ agbegbe naa pẹkipẹki fun itọju to peye, ẹsọ alaabo oju popo si ko awọn oku lọ si yara igbokuu-si ni ileewosan ileewe giga Fasiti Ilọrin ( UITH).

Ọwọade fi kun un pe awọn ti ko ẹru awọn to ṣe kongẹ ijamba ọkọ ọhun si agọ ọlọpaa Bode-Saadu, nijọba ibilẹ Moro, ki aabo le wa fun un. O rọ awọn awakọ pe ki wọn takete si ere asapajude loju popo.

 

 

Ọwọ ọlọpaa atawọn ọlọdẹ tẹ ikọ adigunjale ti wọn jẹ obinrin l’Oṣogbo

Leave a Reply