Eeyan meji ku lasiko ti wọn n lọ sode ariya l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

O kere tan, eeyan meji lo ku loju-ẹsẹ, nigba ti awọn mẹta fara pa yanna-yanna nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ kan to waye niluu Oṣogbo nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, yii.

Ibi ayẹyẹ ọjọọbi kan la gbọ pe awọn eeyan naa n lọ ni Ogo-Oluwa, nigba tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ niwaju ileeṣẹ Atman Ltd, Kọbọngbogbo ẹ, loju-ọna Ikirun si Oṣogbo.

Awọn marun-un ni wọn wa ninu mọto alawọ dudu naa, koda, a gbọ pe ọmọ ọlọjọọbi wa ninu ọkọ pẹlu wọn.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, Adeleke Bayọnle, ṣalaye pe o ṣee ṣe ko jẹ ere aṣapajude lo ṣokunfa ijamba naa.

Amọ ṣa, awọn ti wọn wa nibẹ ti gbe awọn mẹta ti wọn fara pa lọ sile iwosan, nigba ti wọn n reti awọn ajọ ẹsọ oju popo lati waa ko oku meji to wa lẹgbẹẹ titi.

Leave a Reply