Eeyan meji ku, ọpọ fara pa, lasiko tawọn to n ja tikẹẹti kọju ija sawọn ọlọja n’Ibadan

Awọn to ba laya nikan lo le gba agbegbe Iwo Road, niluu Ibadan kọja ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii pẹlu bi awọn to n mojuto awọn gareeji awọn onimọto nipinlẹ naa atawọn ẹgbẹ onimọto ti wọn ti fofin de ti wọn n pe ni yunọnu ṣe kọju ija sira wọn lori ọrọ tikẹẹti ti wọn ni ki awọn kan ja.

ALAROYE gbọ pe eeyan meji lo ku nibi ikọlu naa, nigba ti aọn mi-in fara pa. Awọn to n mojuto gareeji ti wọn pe ni Park Management System, labẹ idari ọga awọn onimọto tẹlẹ, Ọgbẹni Mukaila Lamidi ti gbogbo eeyan mọ si Auxilliary ati awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto. Awọn ti wọn n ta foonu la gbọ pe wọn ni ki wọn maa san awọn owo kan ni agbegbe Baba Onilu ti wọn ti n taja ni Iwo Road. Niṣe ni awọn ọmọ Auxilliary yii ya bo ṣọọbu awọn eeyan naa, bi wọn ṣe n ba ọja wọn jẹ ni wọn n fọ gilaasi awọn ṣọọbu naa, ti wọn si n da kọntena awọn ọlọja nu, n lọrọ ba di bo o lọ o jago..

Ọrọ owo yii lo fa wahala, nigba ti aọn eeyan yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, niṣe ni ibọn n ro lakọlakọ ni gbogbo agbegbe Iwo Road, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ, ti ọrọ si di akọlukọgba.

Bẹẹ lawọn ọlọkada n yipada, ti wọn si n sare buruku lati yọ ninu wahala naa. Nigba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, eeyan meji lo ku lasiko ikọlu naa, bẹẹ ni awọn kan fara pa.

Awọn agbofinro ni wọn pada waa da alaafia pada si agbegbe naa.

Leave a Reply