Eeyan meji ku, ọpọ fara pa, nibi ijamba ọkọ ni Fasiti Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

 

O kere tan, eeyan meji padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si fara pa yanna yanna, nibi ijamba ọkọ to waye laarin ọkọ akero Korope ati ọkọ ayọkẹlẹ kan to kọ lu ara wọn lagbegbe Daamu, loju ọna inu ọgba Fasiti Ilọrin, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii. 

ALAROYE gbọ pe dẹrẹba akero Korope ati obinrin kan to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun ni wọn ku lẹsẹkẹsẹ, ti awọn mi-in si kan lẹṣẹ ti eegun wọn run jegejege.

Mọlẹbi kan naa mẹrin lo wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, iya ati awọn ọmọde meji. Iya ku, awọn ọmọ mejeeji si fara pa kọja afẹnusọ. Bakan naa ni dẹrẹba Korope to ko awọn akẹkọọ Fasiti Ilọrin marun-un ku, ti gbogbo awọn to ko si fara pa. 

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ere asapajude ti awọn awakọ naa sa lo ṣokunfa ijamba ọhun. Wọn ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, ti wọn si ti n gba itọju bayii. Bakan naa ni wọn ti mu idaduro ba eto ẹkọ nileewe naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lati le kẹdun awọn to ku nibi iṣẹlẹ buruku naa.

Leave a Reply