Eeyan meji padanu ẹmi wọn ninu ija ẹgbẹ onimoto l’Ondo

 Jide Alabi

 Eeyan meji lo ti padanu ẹmi wọn ninu wahala ẹgbẹ awọn onimọto to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Akurẹ.

Awọn ẹgbẹ onimọto ti wọn ti pin si meji yii ni wọn doju ija kọ ara wọn ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ Iṣẹgun yii gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ.

Niṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa yọ ada sira wọn, bi wọn ṣe n lu ara wọn nigi ni wọn n ṣa ara wọn ladaa, nigba ti awọn eeyan yoo si fi mọ bo ṣe n ṣẹlẹ, eeyan meji ti ku nibi wahala yii.

Ọpọlọpọ mọto ni wọn bajẹ, bẹẹ ni wọn n lo ọkan-o-jọkan ohun ija oloro lati ba ara wọn ja. Niṣe ni awọn ara agbegbe naa, awọn ọlọja atawọn araalu n sa kijokijo, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Oludamọran Gomina Akeredolu lori iṣẹ akanṣe, Doyin Ọdẹbọwale, kede lorukọ ijọba ipinlẹ Ondo pe awọn ti fofin de awọn ẹgbẹ onimoto naa.

Igbesẹ yii waye lati fun awọn ẹgbẹ mejeeji to n doju ija kọ ara wọn yii lati pade, ki wọn si yanju aawọ to wa laarin wọn, eyi ti ko fi ni i maa sakoba fun awọn araalu to n wọ ọkọ wọn.

Leave a Reply