Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Eeyan mẹjọ lo jona ku raurau lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii nitosi afara Ṣaapade, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Ni deede aago mẹ́sàn-an alẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ.
Alaboojuto ipinlẹ Ogun nileeṣẹ FRSC, Kọmanda Ahmed Umar, ṣalaye pe ọkọ bọọsi kan to jẹ Mazda, to ni nọmba AAA 249 VX, ni taya rẹ fọ lori ere, bi mọto naa ṣe bẹrẹ si i gbokiti niyẹn. O ni nibi to ti n gbokiti naa ni ina ti sọ lara ẹ, bi eeyan mẹjọ ṣe jona ku ninu awọn mọkanla to wa ninu ọkọ naa niyẹn.
Umar ni ẹsẹkẹsẹ ti ijamba naa waye ni FRSC ti kan si ileeṣẹ panapana to wa ni Ṣagamu, lati tete pana wahala yii.
Ileewosan Idẹra to wa ni Sagamu, lo ni awọn ko awọn mẹta tina jo, ṣugbọn ti wọn ko ti i ku lọ, awọn si kan si ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ nitori awọn to ku.
Ọga FRSC naa waa bẹ awọn awakọ pe ki wọn maa ri i daju pe taya ọkọ wọn dara ki wọn too bọ sọna, nitori ijamba taya ki i mọ niwọn, aburu bii iru eyi lo maa n fa nigba gbogbo.