Eeyan mẹrin ku, mẹtala fara pa, ninu ijamba ọkọ l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ko din leeyan mẹrin ti wọn ku, nigba tawọn ero mẹtala tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to waye laarin oju ọna marosẹ Ikaram si Akunnu Akoko, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Ijamba ọkọ yii ni wọn lo waye pẹlu ọkọ bọọsi Toyota elero mejidinlogun kan ti nọmba rẹ jẹ MBA 752 XA lasiko to n lọ sapa ọna Oke-Ọya.

Awakọ bọọsi ọhun lo padanu ijanu ọkọ rẹ lẹyin ti ọkan ninu awọn taya ẹsẹ mọto deedee fọ lojiji lori ere.

Adari ẹṣọ oju popo lagbegbe Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Olurọpo Alabi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin ni loju-ẹsẹ ti awọn kan ti pe awọn lawọn ti sare de ibi ijamba ọhun lati tete doola ẹmi awọn eeyan to ha sinu ọkọ naa.

Alabi ni kiakia lawọn ti gbe awọn to fara pa lọ si ile-iwosan ijọba to wa niluu Ikarẹ. Mọṣuari ọsibitu yii kan naa lo ni awọn tọju oku awọn mẹrin to ku si titi tawọn ẹbi wọn yoo fi yọju.

Ọga ọlọpaa tesan Oke-Agbe Akoko, Ọgbẹni Paullinus Unnah, ni awọn ti gbiyanju lati wọ iyooku ọkọ bọọsi naa lọ si agọ awọn.

Leave a Reply