Eeyan mẹrin ku ninu ijamba ọkọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Eeyan mẹrin ni wọn pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ kan kan to waye niluu Ondo ati agbegbe Ọwẹna loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii.

Iwaju geeti ileewe olukọni agba Adeyẹmi to wa niluu Ondo ni ajalu ọhun ti kọkọ bẹrẹ lọjọ naa pẹlu bi ọkọ bọọsi Toyota elero mejidinlogun kan, ọkọ jiipu ati kẹkẹ Maruwa ṣe kọ lu ara wọn.

Awakọ bọọsi ọhun ni wọn lo ṣeesi kọ lu ọkọ jiipu kan ati kẹkẹ Maruwa lasiko to n sa fun awọn oṣiṣẹ VIO kan ti wọn n ṣayẹwo iwe ọkọ loju ọna marosẹ to gba iwaju kọlẹẹji naa kọja.

Loju-ẹsẹ lo ti tẹ obinrin kan pa nigba tawọn mi-in tun fara pa yannayanna.

Ohun to buru ju ninu iṣẹlẹ ọhun ni bawọn ileewosan ti wọn ko awọn to fara pa lọ ṣe kọ jalẹ lati tọju wọn latari iyansẹlodi awọn dokita ijọba to n lọ lọwọ.

Alẹ ọjọ kan naa ni ijamba ọkọ tun ṣeku pa awọn mẹta mi-in lagbegbe Ọwẹna, loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ ti awọn ero miiran si fara ṣeṣe.

Ohun ta a gbọ lati ẹnu ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ ni pe, ere asapajude ti awakọ akero naa ọhun n sa lo ṣokunfa ijamb naa.

Leave a Reply