Eeyan mẹrin padanu ẹmi wọn ninu ijamba mọto loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan

Jọkẹ Amọri
Eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn ni ifọnafọnṣu ninu ijamba ọkọ kan to waye ni agbegbe Foursquare Gospel Church, to wa ni Ogunmakin, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Ijamba naa gẹgẹ bii agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ oju popo, (FRSC), Ahmed Umar, ṣe fidi rẹ mulẹ fun awọn oniroyin niluu Abẹokuta waye ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ku diẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ ta a ṣẹṣe lo tan yii.
O ni ere asapajude ti awakọ Mazda ti nọmba rẹ jẹ SHK 684XA n sa lo fi lọọ kọ lu ọkọ ajagbe kan ti nọmba rẹ jẹ XA 802KKM, ti mẹrin si ku ninu awọn ero to gbe, bẹẹ ni awọn mẹjọ fara pa. Ọkunrin mejila ati obinrin kan lo ni wọn wa ninu ọkọ naa. Ọkunrin mẹta ati obinrin kan lo ba iṣẹlẹ naa rin.
Ileewosan kan ti wọn n pe ni Victory Hospital, to wa ni Ogere, ni wọn ko awọn to fara pa lọ, ti wọn si ti ko oku awọn mẹrin to gbẹmi-in mi lọ si ile igbokuu-si to wa ni Ipara.
O waa rọ awọn awakọ lati maa ṣọra ṣe, ki wọn si maa pa ofin irinna mọ ni gbogbo igba ti wọn ba n rin lori titi.
Bẹẹ lo ba mọlẹbi aọn tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si kẹdun.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: