Eeyan mẹrinla mi-in tun ko Korona ni Ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ, ni wọn ba ti ẹka ayẹwo ibẹ pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn alaṣẹ Ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ (OOUTH), ni Ṣagamu, ti tilẹkun ẹka to n ṣayẹwo ẹjẹ atawọn nnkan mi-in nibẹ pa latari beeyan mẹrinla mi-in ṣe tun lugbadi arun Korona lẹka naa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni awọn mẹrinla yii ṣayẹwo Korona, iyẹn ninu awọn oṣiṣẹ mẹrindinlogun yooku to wa nibẹ, esi ayẹwo naa si fi han pe awọn mẹrinla ọhun ti ni Korona, bo tilẹ jẹ pe apẹẹrẹ rẹ ko han lara wọn.

Ni bayii, eeyan mẹrinlelọgbọn lo ti ni arun naa lẹka yii.

Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker, fidi ẹka ayẹwo OOUTH ti wọn ti pa yii mulẹ, o ni ọsẹ meji ni yoo fi wa ni titi. Bẹẹ ni wọn ti ya awọn to lugbadi arun naa sọtọ laaye itọju.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lanlọọdu ati getimaanu pa ọmọọdun mẹrin, wọn yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo

Faith Adebọla Diẹ lo ku kawọn araalu tinu n bi dana sun baba getimaanu kan …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: