Eeyan mẹrinla tun ti lugbadi arun  Koronafairọọsi l’Ekiti

 Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Arun Koronafairọọsi tawọn eeyan ro pe o ti dohun igbagbe nipinlẹ Ekiti tun ti pada bayii pẹlu awọn akọsilẹ ati ikede tuntun ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun, Nigeria Centre for Disease Control (NCDC), ṣe.

Laarin ọjọ Aje, Mọnde, to kọja, si ọsan ọjo Aje, Mọnde, ana, eeyan mẹrinla ni NCDC sọ pe o tun ti lugbadi arun naa.

Eeyan marun-un lo ko arun naa lọjọ Aje to kọja, eeyan meji ko o l’Ọjọruu, ẹyọ kan l’Ọjọbọ, meji lọjọ Ẹti, ati mẹrin lọjọ Abamẹta.

Lọwọlọwọ bayii, eeyan marundinnirinwo (395) lo ti lugbadi Korona l’Ekiti, ninu eyi ti mẹtalelọgbọn (33) wa ni ibudo itọju, tawọn mẹfa si ti jẹ Ọlorun nipe.

Ṣaaju ni Gomina Kayọde Fayẹmi ti kede fun gbogbo awọn kọmiṣanna, oludamọran pataki, olori ileeṣẹ ijọba atawọn adari kaakiri ipinlẹ naa lati maa lo ibomu, ki wọn si maa tẹle ofin to n gbogun ti Koronafirọọsi. Fayẹmi kilọ pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin naa yoo jiya.

 

Leave a Reply