Ko din leeyan mẹrinlelogun (24) to doloogbe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹjọ, ninu mọlẹbi kan ṣoṣo. Ounjẹ ni gbogbo agboole jẹ to fa iku ojiji yii, wọn ko mọ pe majele lawọn bu sounjẹ naa dipo iyọ, ohun to fa iku wọn niyẹn.
Abule Danzanke, nijọba ibilẹ Isa, nipinlẹ Sokoto, niṣẹlẹ yii ti waye.
Kọmiṣanna eto ilera nibẹ, Ali Inname, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pẹlu alaye pe mọlẹbi ni gbogbo awọn to ku yii, bii ọmọ ẹgbọn, ọmọ aburo, iya atawọn baba gbogbo ni wọn n gbe agboole gẹgẹ bii iṣe wọn.
Kọmiṣanna ṣalaye pe kinni kan ti wọn n pe ni ‘Gishrin Laale’ lawọn to dana fẹbi naa fi se ounjẹ, wọn ṣe bi iyọ ni, bẹẹ majele aṣekupani ni. Bi wọn ṣe n jẹ ounjẹ ti wọn fi se tan ni gbogbo ile bẹrẹ si i kigbe inu rirun, gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi wọn ko si so eso rere kan, pabo lo ja si.
Nigba ti wọn yoo fi ka iye eeyan to ti jẹ Ọlọrun ni pe gẹge bo ṣe wi, wọn jẹ mẹrinlelogun. Ali sọ pe afi awọn obinrin meji kan ti wọn ko jẹ ounjẹ naa lajẹyo, to jẹ wọn kan tọ ọ wo diẹ nikan ni ko ku, ṣugbọn awọn naa de ileewosan, alaafia si ti n to wọn latari itọju ti wọn n fun wọn.
O rọ awọn eeyan ilu naa lati fi kun imọtoto wọn, paapaa nipa ohun ti wọn n jẹ.
Kọmiṣanna eto ilera rọ wọn lati maa pa kanga ti wọn n mu de, ki wọn ma jẹ ki maaluu maa ṣegbọnsẹ sibẹ, ki wọn si tẹle gbogbo ofin imọtoto, ki iku ọwọọwọ bayii le kasẹ nilẹ laarin wọn.