Eeyan mẹsan-an ku lojiji, kontena lo re lu ọkọ akero l’Oju-Ẹlẹgba 

Ọrẹoluwa Adedeji

Eeyan mẹsan-an, ninu eyi ti ọkunrin agbalagba mẹrin, obinrin mẹta atawọn ọmọ kekere meji, ọkunrin kan ati obinrin kan ni wọn pade iku ojiji nigba ti kọntena to ko ẹru re lu mọto wọn ni agbegbe Oju-Ẹlẹgba, nijọba ibilẹ Surulere, nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

ALAROYE gbọ latẹnu awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ni ọkọ danfo naa n kero ni abẹ biriiji, ibẹ ni kọntena to ga to bii iwọn ẹsẹ bata ogun to ko ẹru ti re lu u nibi to ti n ju ọwọ balabala lasiko to n pẹwọ fun koto, Niṣe lo si rẹ ọkọ naa pẹtẹpẹtẹ pẹlu aọn ero to wa ninu rẹ.

Ọpọ eeyan ni wọn lo tun fara pa yanna yanna, ṣugbọn ori ko obinrin kan yọ ninu iṣẹlẹ naa, oun nikan la gbọ pe wọn ri fa jade laaye ninu ijamba ọhun.

Ninu ọrọ ọga ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Dokita Fẹmi Oke-Ọsanyintolu, o ṣalaye pe ‘‘awọn eeyan adugbo Oju-Ẹlẹgba ni wọn ranṣẹ pajawiri pe kọntena kan ti ṣubu lu ọkọ akero kan pẹlu ero inu rẹ. Nigba ta a debẹ, a ba kọntena naa to to ẹsẹ bata ogun lori ọkọ akero ọhun.

‘‘Iwadii ta a ṣe fi han pe niṣe ni ọkọ akero yii duro si abẹ biriiji naa to n ko ero, lasiko naa ni ọkọ ti kọntena yii wa lori rẹ naa n bọ, ṣugbọn niṣe ni dẹrẹba ọkọ naa ko le dari rẹ mọ nibi to ti n pẹwọ fun koto, to si bẹrẹ si i fi kaakiri, ko too lọ wo lu ọkọ yii lori nibi ẹgbẹ biriiji to ti n kero.

‘‘Pẹlu iranlọwọ awọn irinṣẹ wa la fi gbe kọntena naa kuro lori ọkọ akero yii. Obinrin kan ṣoṣo la ri gbe jade laaye, ti a si sare gbe e lọ si ileewosan to wa nitosi fun itọju pajawiri.

Eeyan mẹsan-an ni wọn lo ku ninu ijamba naa, ọkunrin agbalagba mẹrin, awọn obinrin mẹta, ọmọde kan to jẹ ọkunrin ati ọdọmọbinrin kan.

Leave a Reply