Eeyan mẹta ku nibi ijamba ina to ṣẹlẹ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Eeyan mẹta, mọto marun-un ati ọkada meji lo jona deeru laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, nigba ti tanka to gbe epo bẹntiroolu padanu ijanu ẹ lasiko to n sọkalẹ lori biriiji Kutọ, nitosi banki GTB, l’Abẹokuta.

Gẹgẹ bawọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣe ṣalaye, wọn ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ni ijamba yii waye.  Nigba ti tanka epo naa fẹẹ sọkalẹ lori afara naa ni ijanu rẹ ko mu un mọ, bo ṣe ṣubu niyẹn ti epo inu ẹ danu, ni ina nla ba sọ.

Awọn eeyan to wa nitosi, mọto ti wọn paaki sibẹ pẹlu ọkada ni ina ọhun ka mọ, to si jo wọn pa. Bẹẹ ni wọn ni awọn mi-in tun fara pa.

Kọmandanti Ahmed Umar, ọga FRSC nipinlẹ Ogun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni eeyan mẹta lo ku loootọ, ọpọ lo si fara pa nigba tọwọ ina ọhun ba wọn.

Ọsibitu FMC to wa n’Idi-Aba, l’Abẹokuta, lo ni wọn ko awọn to ṣalaisi atawọn to ṣeṣe naa lọ.

Umar lawọn ko ti i mọ ohun to fa ina ojiji yii, o lawọn ṣi n ṣewadii ẹ ni.

Bakan naa ni Kọmiṣanna fawọn akanṣe iṣẹ nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Fẹmi Ogunbanwo to ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa sọ pe ijọba yoo duro de aabọ iwadii awọn ajọ kọọkan ti ọrọ yii kan kawọn too ṣalaye kikun lori ẹ.

O fi kun un pe ijọba yoo sanwo itọju awọn to fara pa nibẹ, nitori iṣẹlẹ naa ti de etiigbọ Gomina Dapọ Abiọdun.

 

Leave a Reply