Eeyan mẹta ku ninu mọlẹbi kan, majele ni wọn jẹ mọ amala n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu Ilọrin,

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni eeyan mẹta ninu mọlẹbi kan tun ku lojiji lẹyin ti wọn jẹ amala to ni majele ninu lagbegbe Centre Igboro, nijọba ibilẹ Ila- Oorun Ilọrin (East), nipinlẹ Kwara, ti mẹta ninu wọn si gba’bẹ lọ sọrun.

Baba awọn ọmọ ọhun sọ fun ALAROYE pe lẹyin ti awọn ọmọ oun marun-un jẹ amala tan ni mẹta ninu wọn bẹrẹ si i bi, awọn si sare ko wọn lọ sileewosan ọlọmọ wẹwẹ, ni Centre Igboro, ṣugbọn awọn mẹtẹẹta lo ku loju-ẹṣẹ, tawọn si ti gbe awọn meji to ku lọ sileewosan ijọba n’Ilọrin, ti wọn si wa ni alaafia bayii.

Baba awọn ọmọ ọhun sọ pe iṣẹ agbẹ loun yan laayo, ati pe oun gan-an loun peṣe elubọ ti wọn fi ro amala naa funra oun, sugbọn oun ko mọ ohun to fa a.

Nigba ti ALAROYE pe Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ alaabo (NSCDC), ni Kwara, Babawale Zaid Afolabi, o ni ajọ awọn ko ti i gbọ si iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply