Eeyan mẹta ku, ọpọ fara pa, nibi ija ọlọpaa ati akẹkọọ Kwara Poli n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ọrọ di bo o lọ o yago lọna, lowurọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lagbegbe Lajọlọ, Ọyun, Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lasiko tawọn ọlọpaa atawọn akẹkọọ Kwara Poli fija pẹẹta, eeyan mẹta lo ku, ti ọpọ si fara pa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ ọjọ Abamẹtani awọn ọlọpaa kan ya bo agbegbe Lajọlọ, ti wọn n wa awọn ọmọ yahoo kiri, ti wọn si n wọ gbogbo inu ile kaakiri. Eyi lo ṣokunfa rogbodiyan laarin awọn akẹkọọ Kwara Poli ati ọlọpaa, ti eeyan mẹta si ba iṣẹlẹ naa lọ. Kapẹnta kan ati gende kan ti wọn pe ni Jamiu wa ara awọn ti ọta ibọn ba lasiko to fẹẹ maa yaworan iṣẹlẹ ọhun, ati ẹnikan ti wọn o darukọ rẹ.

Ṣugbọn ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, o sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni awọn ọlọpaa lọọ ka mọ ibuba wọn to fi di yanpọnyanrin, ti ẹmi kan si bọ. O ni awọn gbe awọn to fara pa lọ si ileewosan, ati pe ṣaaju ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti pa akẹkọọ Fasiti KWASU kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, niluu Malete, nipinlẹ Kwara. O tẹsiwaju pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lo dena de awọn ọlọpaa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera, ti ọwọ awọn agbofinro yii si pada tẹ ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Musbau.

Leave a Reply