Eeyan mẹta ku sinu ijamba ọkọ l’Agọ Ọka Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn ku sinu ijamba ọkọ to waye ni Agọ-Ọka Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ ta a ṣẹṣẹ lo tan yii.

Ijamba yii ṣẹlẹ laarin Toyota Hillux  ati ọkọ ayọkẹlẹ kan, ọkan ninu awọn awakọ ọhun ni wọn lo padanu ijanu rẹ, leyii to ṣokunfa bo ṣe lọọ kọ lu eyi to n bọ loju ọna tìrẹ.

Loju-ẹsẹ leeyan mẹta ti ku, nigba tawọn mi-in si tun fara pa ninu awọn ọkọ mejeeji.

Gbogbo awọn to ṣeṣe ni wọn sare ko lọ sile iwosan aladaani kan to wa nitosi, latari iyansẹlodi awọn oṣiṣẹ eleto ilera to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo.

Leave a Reply