Wọn ṣi n wa eeyan mẹta tawọn ajinigbe ji l’Ondo

Jide Alabi

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn agbofinro ṣi n wa awọn mẹta kan ti wọn ji gbe nipinlẹ Ondo lọsẹ to kọja yii.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Ikakumọ, nipinlẹ Ondo, lawọn janduku ajinigbe ti ji awọn eeyan mẹta gbe bayii.

Ilu kan ti wọn ti ji wọn gbe yii lo paala laarin ipinlẹ Ondo ati Edo. Arinrin-ajo ni wọn pe wọn, ati pe ijọba ibilẹ Ariwa-Akoko ni wọn ti ji gbe wọn.

Ọkunrin ọlọkada kan ti awọn ajinigbe ọhun ti lu niluku, to raaye bọ mọ wọn lọwọ lo lọọ fọrọ ọhun to awọn agbofinro leti.

Igbakeji komiṣanna ọlọpaa, nipinlẹ naa, Razak Rauf, ti sọ pe ootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe iwadii ti bẹrẹ lati tu aṣiri awọn aṣebajẹ ọhun, ti awọn yoo si wa awọn ti wọn ji gbe ọhun ri.

 

Leave a Reply