Eeyan mẹtadinlogun jona ku ninu ijamba ọkọ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Eeyan mẹtadinlogun lo jona ku ninu ijamba ọkọ to gbẹmi ogun eeyan lọjọ Abamẹta, Satide, niluu Ọlọkọnla, lọna titi marosẹ Bode-Saadu si Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ere asapajude lo ṣokunfa ijamba ọhun, ọkọ mẹta ọtọọtọ lo lọọ kọlu ara wọn tina si ṣẹ yọ loju ẹsẹ. Ṣugbọn, ori ko ẹni kan ṣoṣo yọ lara awọn ero inu ọkọ, o si jade laaye lai ni ifarapa kankan.

Awọn ọkọ to nijamba ọhun ni, ọkọ akẹru Mark ti nọmba rẹ jẹ, GGE 614XM, ọkọ akẹru Mitsubishi mi-in ti nọmba rẹ je, BRK534YX ati ọkọ akero Toyota Hummer ti nọmba rẹ jẹ, KEY479YE.

 

Lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe lasiko ti awakọ bọọsi Toyota naa n wa ọna lati pẹ ọkọ akẹru to ko ata silẹ lo lọọ fori sọ ọkọ kan to n bọ niwaju rẹ, lojiji ni ina sọ.

Ọga agba ajọ to n mojuto irina oju popo, FRSC, ẹka ipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, ati akẹgbẹ rẹ tileeṣẹ panapana, Falade Olumuyiwa John, ti wọn fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ panpana doola ẹni kan, ṣugbọn awọn mẹtadinlogun jona kọja idanimọ.

Ọwọade ni awọn mọkanla lo fara pa ninu ijamba naa, wọn ti ko wọn lọ silewosan aladaani kan, Aduagba Clinic & Maternity, to wa ni Ọlọkọnla, nibi ti wọn ti n tọju wọn. O ni awọn to ku ti wa ni mọṣuari.

Leave a Reply